+ -

عن ثَوْبَانَ رضي الله عنه قال:
كَانَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ إِذَا انْصَرَفَ مِنْ صَلَاتِهِ اسْتَغْفَرَ ثَلَاثًا، وَقَالَ: «اللَّهُمَّ أَنْتَ السَّلَامُ، وَمِنْكَ السَّلَامُ، تَبَارَكْتَ ذَا الْجَلَالِ وَالْإِكْرَامِ»، قَالَ الْوَلِيدُ: فَقُلْتُ لِلْأَوْزَاعِيِّ: كَيْفَ الْاسْتِغْفَارُ؟ قَالَ: تَقُولُ: أَسْتَغْفِرُ اللهَ، أَسْتَغْفِرُ اللهَ.

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 591]
المزيــد ...

Lati ọdọ Thaoban- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti pari irun o maa n wa aforijin lẹẹmẹta, o maa sọ pé: “Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikroom”, Al-Waleed sọ pé: Mo sọ fun Al-‘Aozaa’iy: Bawo ni a ṣe maa n wa àforíjìn? O sọ pe: Waa sọ pe: Astagfirullah, Astagfirullah.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 591]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti pari irun o maa n sọ pe: Astagfirullah, Astagfirullah, Astagfirullah.
Lẹyin naa o maa gbe Oluwa rẹ tobi pẹlu sisọ pé: “Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikrọọm” Ọlọhun ni Ọba Àlàáfíà ti O pe nibi awọn iroyin Rẹ, ti a fọmọ kuro nibi gbogbo aleebu ati adinku, ti o si n wa lílà lọdọ Rẹ kuro nibi awọn aburu aye ati ọrun ti ko ki n ṣe lọdọ ẹni ti o yatọ si I, Oun- mimọ ni fun Un- ni daadaa Rẹ pọ ni aye ati ọrun, Ẹni ti O ni titobi ati daadaa.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe wiwa àforíjìn ni nnkan ti a fẹ lẹyin irun ati didunni mọ ọn.
  2. Ṣíṣe wiwa àforíjìn ni nnkan ti a fẹ lati wa pipe adinku to wa nibi ijọsin ati lati dí àáyẹ fun itẹle ati aṣeeto to wa nibẹ.
Àlékún