عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«مَنْ سَبَّحَ اللهَ فِي دُبُرِ كُلِّ صَلَاةٍ ثَلَاثًا وَثَلَاثِينَ، وَحَمِدَ اللهَ ثَلَاثًا وَثَلَاثِينَ، وَكَبَّرَ اللهَ ثَلَاثًا وَثَلَاثِينَ، فَتْلِكَ تِسْعَةٌ وَتِسْعُونَ، وَقَالَ: تَمَامَ الْمِائَةِ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ غُفِرَتْ خَطَايَاهُ وَإِنْ كَانَتْ مِثْلَ زَبَدِ الْبَحْرِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 597]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayra- ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-:
«Ẹni ti o ba ṣe afọmọ fun Ọlọhun (Subhānallāh) ni ẹyin gbogbo irun kọọkan ni igba mẹtalelọgbọn, ti o si tun dupẹ fun Ọlọhun (AlhamduliLlāhi) ni igba mẹtalelọgbọn, ti o tun wa gbe titobi fun Ọlọhun (Allāhu akbar) ni igba mẹtalelọgbọn, ìyẹn jẹ ọgọrun din ẹyọkan, ti o wa sọ ni ipari ọgọ́rùn-ún pe: Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa alā kulli shayhin qadīr, wọn o fi ori gbogbo ẹṣẹ rẹ jin in kódà ki o to deede fóòmù ori omi okun».
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 597]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ẹni ti o ba sọ lẹyin ti o ba pari awọn irun ọranyan:
Ni igba mẹtalelọgbọn pe: “Subhaanollooh”, oun naa ni mimọ Ọlọhun kuro nibi àléébù.
Ati ni igba mẹtalelọgbọn: "AlhamduliLlāhi" oun naa ni yiyin In pẹlu awọn iroyin pipe pẹlu inifẹẹ Rẹ ati gbigbe E tobi.
Ati ni igba mẹtalelọgbọn: "Allāhu akbar” oun ni pe Ọlọhun ni O tobi ju Oun si ni O gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ.
ki o mu onka naa pe ọgọ́rùn-ún pẹlu gbolohun: "Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa ala kulli shayhin qadeer" itumọ rẹ si ni pe: Ko si ẹni ti ijọsin tọ si pẹ̀lú ẹtọ ayaafi Ọlọhun ni Oun nikan ṣoṣo ko si orogun fun Un, ati pe Oun- mimọ n bẹ fun Un- nìkan ni O ni ìjọba ti o pe, ti O si lẹtọọ si ẹyin pẹlu ifẹ ati igbetobi yatọ si ẹlòmíràn tí ó yatọ si I, ati pe Oun ni Olukapa ti nkankan o si le da A ni agara.
Ẹni ti o ba wa sọ ìyẹn wọn yio pa aṣiṣe rẹ rẹ wọn o si ṣe aforijin rẹ, koda ki o pọ bi foomu funfun ti maa n leke omi okun nígbà tí o ba n ru soke.