+ -

عَنْ أَبِي أُمَامَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«مَنْ قَرَأَ آيَةَ الْكُرْسِيِّ فِي دُبُرِ كُلِّ صَلَاةٍ مَكْتُوبَةٍ لَمْ يَمْنَعْهُ مِنْ دُخُولِ الْجَنَّةِ إِلَّا أَنْ يَمُوتَ».

[صحيح] - [رواه النسائي في الكبرى] - [السنن الكبرى للنسائي: 9848]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Umāmah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu ni ẹyin irun ọranyan kọọkan, ko si nkan ti yio di i lọwọ wiwọ al-jannah ayaafi ki o ku.

[O ni alaafia] - - [As-Sunanul Kubrọ ti An-Nasaaiy - 9848]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu lẹyin ipari irun ọranyan, ko si nkankan ti o le ma jẹ ki o wọ alujanna ayaafi iku; o si wa ninu sūratul Baqorah, gbolohun Ọlọhun ti ọla rẹ ti o sọ pe: {Allahu la ilaha illa Huwa al-Hayyu al-Qayyoomu la ta‘khuthuHu sinatun wala nawmun laHu ma fis samāwāti wama fil ardi man dha ladhī yashfa‘u indaHu illa bi-idhniHi ya‘lamu mā bayna aydīhim wamā khalfahum wala yuhītūna bishayin min ‘ilmiHi illa bimā shaa'a wasi‘a kursiyyuHus samāwāti wal-arda wala ya’ūduHu hifdhuhumā waHuwal ‘aliyyu alAadhīm} [Al-Baqorah: 255]

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti o n bẹ fun aayah ti o tobi yii; latari nkan ti o ko sinu ninu awọn orukọ to rẹwa ati awọn iroyin ti o ga.
  2. Ṣiṣe lẹtọọ kika aayah ti o tobi yẹn lẹyin gbogbo irun ọranyan.
  3. Awọn iṣẹ oloore jẹ okunfa wiwọ al-jannah.