عن أَبي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه:
أنه كَانَ يُكَبِّرُ فِي كُلِّ صَلَاةٍ مِنَ الْمَكْتُوبَةِ وَغَيْرِهَا، فِي رَمَضَانَ وَغَيْرِهِ، فَيُكَبِّرُ حِينَ يَقُومُ، ثُمَّ يُكَبِّرُ حِينَ يَرْكَعُ، ثُمَّ يَقُولُ: سَمِعَ اللهُ لِمَنْ حَمِدَهُ، ثُمَّ يَقُولُ: رَبَّنَا وَلَكَ الْحَمْدُ، قَبْلَ أَنْ يَسْجُدَ، ثُمَّ يَقُولُ: اللهُ أَكْبَرُ حِينَ يَهْوِي سَاجِدًا، ثُمَّ يُكَبِّرُ حِينَ يَرْفَعُ رَأْسَهُ مِنَ السُّجُودِ، ثُمَّ يُكَبِّرُ حِينَ يَسْجُدُ، ثُمَّ يُكَبِّرُ حِينَ يَرْفَعُ رَأْسَهُ مِنَ السُّجُودِ، ثُمَّ يُكَبِّرُ حِينَ يَقُومُ مِنَ الْجُلُوسِ فِي الِاثْنَتَيْنِ، وَيَفْعَلُ ذَلِكَ فِي كُلِّ رَكْعَةٍ، حَتَّى يَفْرُغَ مِنَ الصَّلَاةِ، ثُمَّ يَقُولُ حِينَ يَنْصَرِفُ: وَالَّذِي نَفْسِي بِيَدِهِ، إِنِّي لَأَقْرَبُكُمْ شَبَهًا بِصَلَاةِ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، إِنْ كَانَتْ هَذِهِ لَصَلَاتَهُ حَتَّى فَارَقَ الدُّنْيَا.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 803]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-:
O maa n kabara nibi gbogbo irun ninu eyi ti o jẹ ọran-anyan ati eyi ti o yatọ si i, ninu Ramadan ati oṣu ti o yatọ si i, o maa n kabara nigba ti o ba dìde, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba rukuu, lẹyin naa o maa n sọ pe: Sami’alloohu liman hamidaHu, lẹyin naa o maa n sọ pe: Robbanaa wa laKal hamdu, ṣíwájú ki o to forikanlẹ, lẹyin naa o maa n sọ pe: Allahu Akbar nigba ti o ba lọ silẹ ni ẹni ti o forikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba forikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba dide lati ijokoo nibi rakah meji naa; o maa n ṣe bẹẹ nibi gbogbo rakah, titi o maa fi pari irun, lẹyin naa o maa n sọ ti o ba ti n lọ pe : Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju emi ni irun mi jọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ju ninu yin, eleyii si ni irun rẹ titi o fi fi aye silẹ.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 803]
Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- gba apakan wa ninu bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe maa n kirun, o wa sọ pe ti o ba fẹ kirun, o maa n kabara nigba ti o ba dide fun kabara wiwọ irun, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba n lọ si rukuu, ati nigba ti o ba fẹ forikanlẹ, ati nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, ati nigba ti o ba forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹlẹẹkeji, ati nigba ti o ba gbe ori rẹ dide kuro nibẹ, ati nigba ti o ba dide lati rakah meji akọkọ lẹyin ti o ba jokoo fun ataya akọkọ nibi irun oni rakah mẹta tabi oni rakah mẹrin, lẹyin naa o maa n ṣe bẹẹ nibi gbogbo irun pata titi o maa fi pari rẹ, o maa n sọ ti o ba ti gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu pe: Sami’alloohu liman hamidaHu, lẹyin naa o maa n sọ ti o ba wa ni iduro pe: Robbanaa wa laKal hamdu.
Lẹyin naa Abu Huraira maa n sọ ti o ba ti pari irun pé: Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju ẹmi ni ìrun mi jọ irun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jù, bi o ṣe maa n kirun nìyí titi o fi fi aye silẹ.