عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللهُ عنه سَمِعْتُ رَسُولَ اللهِ صلى الله عليه وسلم يَقُولُ:
«قَالَ اللهُ تَعَالَى: قَسَمْتُ الصَّلَاةَ بَيْنِي وَبَيْنَ عَبْدِي نِصْفَيْنِ، وَلِعَبْدِي مَا سَأَلَ، فَإِذَا قَالَ الْعَبْدُ: {الْحَمْدُ لِلهِ رَبِّ الْعَالَمِينَ}، قَالَ اللهُ تَعَالَى: حَمِدَنِي عَبْدِي، وَإِذَا قَالَ: {الرَّحْمَنِ الرَّحِيمِ}، قَالَ اللهُ تَعَالَى: أَثْنَى عَلَيَّ عَبْدِي، وَإِذَا قَالَ: {مَالِكِ يَوْمِ الدِّينِ}، قَالَ: مَجَّدَنِي عَبْدِي، -وَقَالَ مَرَّةً: فَوَّضَ إِلَيَّ عَبْدِي-، فَإِذَا قَالَ: {إِيَّاكَ نَعْبُدُ وَإِيَّاكَ نَسْتَعِينُ}، قَالَ: هَذَا بَيْنِي وَبَيْنَ عَبْدِي وَلِعَبْدِي مَا سَأَلَ، فَإِذَا قَالَ: {اهْدِنَا الصِّرَاطَ الْمُسْتَقِيمَ، صِرَاطَ الَّذِينَ أَنْعَمْتَ عَلَيْهِمْ غَيْرِ الْمَغْضُوبِ عَلَيْهِمْ وَلا الضَّالِّينَ}، قَالَ: هَذَا لِعَبْدِي وَلِعَبْدِي مَا سَأَلَ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 395]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ pé: Mo pin irun laaarin Mi ati ẹru Mi si meji ọgbọọgba, ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere o maa jẹ tirẹ, ti ẹru Mi ba sọ pe: (Alhamdu lillaahi Rabbil ‘aalameen), Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa sọ pé: Ẹru Mi dupẹ fun mi, ti o ba sọ pe: (Ar-Rahmaanir-Raheem), Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa sọ pé: Ẹru Mi yin Mi, ti o ba sọ pe: (Maaliki Yawmid-Deen), O maa sọ pé: Ẹru Mi gbe Mi tobi, -O tun maa sọ nígbà miran pe: Ẹru mi fi ọrọ rẹ le Mi lọwọ-, ti o ba sọ pe: (Iyyaaka na’budu wa lyyaaka nasta’een), O maa sọ pe: Eleyii wa laaarin Mi ati ẹrú Mi ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ, ti o ba wa sọ pe: (Ihdinas-Siraatal-Mustaqeem, Siraatal-lazeena an’amta ‘alaihim ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen), O maa sọ pe: Eleyii jẹ ti ẹru Mi ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 395]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- sọ ninu hadiiisi Qudusiy pe: Mo pin Suratul Fatiha lori irun laaarin Mi ati ẹru Mi si meji ọgbọọgba, idaji fun mi, ati idaji fun un.
Idaji rẹ akọkọ je: Ọpẹ ati ẹyin ati gbigbe titobi fun Ọlọhun, wọn maa san an ni eyi ti o daa ninu ẹsan lori rẹ.
Idaji rẹ keji jẹ: Idirẹbẹẹ ati àdúrà, Mo maa gba a Mo si maa fun un ni nnkan ti o beere.
Ti Olukirun ba sọ pe: (Alhamdu lillaahi Rabbil ‘aalameen) Ọlọhun maa sọ pé: Ẹru Mi dupẹ fun Mi, ti o ba sọ pe: (Ar-Rahmaanir-Raheem), Ọlọhun maa sọ pé: Ẹru Mi yin Mi o si jẹwọ kikari idẹra Mi lori ẹda Mi, ti o ba wa sọ pe: (Maaliki Yawmid-Deen), Ọlọhun maa sọ pé: Ẹru Mi gbe Mi tobi, o si jẹ iyi ti o gbòòrò.
Ti o ba sọ pe: (Iyyaaka na’budu wa lyyaaka nasta’een), Ọlọhun maa sọ pe: Eleyii wa laaarin Mi ati ẹru Mi.
Idaji akọkọ ninu awọn ayah yii jẹ ti Ọlọhun, Oun naa ni: (Iyyaaka na’budu) oun ni ijẹwọ pe Ọlọhun ni O ni ẹtọ si ìjọsìn, ati idahun pẹlu ijọsin, ati pe pẹlu rẹ ni idaji ti o jẹ ti Ọlọhun fi wa si opin.
Ati pe idaji keji ninu ayah naa, oun ni ti ẹru: (lyyaaka nasta’een) wiwa iranlọwọ lati ọdọ Ọlọhun, ati ṣiṣe adehun Rẹ pẹlu ṣíṣe iranlọwọ.
Ti o ba wa sọ pe: (Ihdinas-Siraatal-Mustaqeem * Siraatal-lazeena an’amta ‘alaihim ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen), Ọlọhun maa sọ pé: Eleyii jẹ idirẹbẹẹ ati adura lati ọdọ ẹru Mi, ati pe nnkan ti ẹru Mi ba beere, o maa jẹ tirẹ, dajudaju Mo ti gba adura rẹ.