عَن ابْنِ عُمَرَ رضي الله عنهما:
أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَانَ يَرْفَعُ يَدَيْهِ حَذْوَ مَنْكِبَيْهِ إِذَا افْتَتَحَ الصَّلَاةَ، وَإِذَا كَبَّرَ لِلرُّكُوعِ، وَإِذَا رَفَعَ رَأْسَهُ مِنَ الرُّكُوعِ، رَفَعَهُمَا كَذَلِكَ أَيْضًا، وَقَالَ: «سَمِعَ اللَّهُ لِمَنْ حَمِدَهُ، رَبَّنَا وَلَكَ الحَمْدُ»، وَكَانَ لاَ يَفْعَلُ ذَلِكَ فِي السُّجُودِ.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 735]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji-:
Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji si deedee ejika rẹ mejeeji ti o ba ti bẹ̀rẹ̀ irun, ati ti o ba ti kabara fun rukuu, ati ti o ba gbe ori rẹ dide lati rukuu, o maa gbe mejeeji bákannáà, o si maa sọ pé: "Sami'alloohu liman hamidaHu, Robbanaa wa laKal hamdu", ko ki n ṣe bẹẹ nibi iforikanlẹ.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 735]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n gbe ọwọ rẹ mejeeji soke nibi aaye mẹta ninu irun ni iwájú ejika ti o ṣe pe: Oun ni ibi ti egungun ejika ati apa ti papọ.
Aaye akọkọ: Ti o ba ti bẹ̀rẹ̀ irun nibi kikabara iwọ irun.
Ikeji: Ti o ba ti kabara fun rukuu.
Ikẹta: Ti o ba ti gbe ori rẹ sókè lati rukuu, ti o wa sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu Robbanaa wa laKal hamdu.
Ko ki n gbe ọwọ rẹ mejeeji sókè nibi ìbẹ̀rẹ̀ fifi ori kanlẹ, tabi nibi gbigbe ori sókè lati ibẹ.