عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ:
كَانَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، إِذَا كَبَّرَ فِي الصَّلَاةِ، سَكَتَ هُنَيَّةً قَبْلَ أَنْ يَقْرَأَ، فَقُلْتُ: يَا رَسُولَ اللهِ بِأَبِي أَنْتَ وَأُمِّي أَرَأَيْتَ سُكُوتَكَ بَيْنَ التَّكْبِيرِ وَالْقِرَاءَةِ، مَا تَقُولُ؟ قَالَ «أَقُولُ: اللهُمَّ بَاعِدْ بَيْنِي وَبَيْنَ خَطَايَايَ كَمَا بَاعَدْتَ بَيْنَ الْمَشْرِقِ وَالْمَغْرِبِ، اللهُمَّ نَقِّنِي مِنْ خَطَايَايَ كَمَا يُنَقَّى الثَّوْبُ الْأَبْيَضُ مِنَ الدَّنَسِ، اللهُمَّ اغْسِلْنِي مِنْ خَطَايَايَ بِالثَّلْجِ وَالْمَاءِ وَالْبَرَدِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 598]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jẹ ẹni ti o ṣe pe, ti o ba ti kabara nibi irun, o maa n dakẹ fun igba díẹ̀ ṣíwájú ki o to ka Fatiha, mo wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun mo fi baba mi ati iya mi ṣe ìràpadà fún ọ, njẹ o ri idakẹ rẹ laaarin kikabara ati kika Fatiha, ki ni nnkan ti o maa n sọ? O sọ pe "mo maa n sọ pe: Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi Al-Lahumma Naqqinī Min Khaţāyāya Kamā Yunaqqá Ath-Thawbu 'Illābyađu Mina Ad-Danasi Al-Lahumma Aghsilnī Min Khaţāyāya Bith-Thalji Wa Al-Mā'i Wa Al-Barad".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 598]
Ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ti kabara, o maa n dakẹ ni idakẹ díẹ̀ ṣíwájú ki o to ka Fatiha, o maa n bẹ̀rẹ̀ irun rẹ nibẹ pẹlu awọn adura kan, ninu eyi ti o wa ninu awọn adura yii ni ọrọ rẹ pé: "Al-Lahumma Bā`id Baynī Wa Bayna Khaţāyāya Kamā Bā`adta Bayna Al-Mashriqi Wa Al-Maghribi Al-Lahumma Naqqinī Min Khaţāyāya Kamā Yunaqqá Ath-Thawbu 'Illābyađu Mina Ad-Danasi Al-Lahumma Aghsilnī Min Khaţāyāya Bith-Thalji Wa Al-Mā'i Wa Al-Barad", O maa n bẹ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- lati gbe awọn àṣìṣe jìnnà si oun ki oun ma ko si i, ni igbejinna kan ti ipadepọ ko lee ṣẹlẹ pẹlu rẹ, gẹgẹ bi ko ṣe le si ìpàdépọ̀ laaarin ibuyọ oorun ati ibuwọ oorun láéláé, ti oun ba wa ko si i, ki O fọ oun mọ kuro nibẹ ki O mu u kúrò bi wọn ṣe maa n mu ìdọ̀tí kuro lara aṣọ funfun, pe ki O fọ oun mọ kuro nibi awọn àṣìṣe rẹ ki O bu tutu si eyi ti o n jo ti o si gbóná nibẹ, pẹlu awọn nǹkan ti n mọ́ nǹkan ti o tutu yìí; omi ati yinyin.