عَنْ أَنَسٍ رضي الله عنه قَألَ:
كَانَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ إِذَا دَخَلَ الخَلاَءَ قَالَ: «اللَّهُمَّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ مِنَ الخُبُثِ وَالخَبَائِثِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 142]
المزيــد ...
Lati ọdọ Anas - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wọ aaye ẹgbin yio sọ pe: «Allaahummọ inni a‘uudhu biKa minal khubuthi wal khabaaithi».
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 142]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wọ aaye ti yio ti biiya bukaata rẹ, itọ tabi igbẹ, yio wa iṣọra pẹlu Ọlọhun, yio si tun sa di I ki O la a nibi aburo awọn eṣu ni takọ tabi tabo. Wọn si tu al-khubuthi ati al-khabaaith sí aburu ati awọn ẹgbin.