عَنْ أَبِي الدَّرْدَاءِ رضي الله عنه أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«مَا شَيْءٌ أَثْقَلُ فِي مِيزَانِ الْمُؤْمِنِ يَوْمَ القِيَامَةِ مِنْ خُلُقٍ حَسَنٍ، وَإِنَّ اللَّهَ لَيُبْغِضُ الفَاحِشَ البَذِيءَ».
[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي] - [سنن الترمذي: 2002]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Dardā'i - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ko si nkankan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ti o to iwa daadaa, ati pe dajudaju Ọlọhun a maa korira onibajẹ onisọkusọ».
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ni wọn gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2002]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju nkan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ninu awọn iṣẹ ati awọn ọrọ ni iwa daadaa, ati pe ìyẹn n bẹ pẹlu titu oju ka, ati kika ṣuta kuro, ati ṣiṣe daadaa. Ati pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga korira ẹni ti ko dara nibi iṣe rẹ ati ọrọ rẹ, ẹni ti maa n fi ahọn rẹ sọ ibajẹ.