عن ابن عمر رضي الله عنهما قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«كل مُسْكِرٍ خَمْرٌ، وكل مُسْكِرٍ حرام، ومن شرِب الخمر في الدنيا فمات وهو يُدْمِنُهَا لَمْ يَتُبْ، لَمْ يَشْرَبْهَا في الآخرة».
[صحيح] - [رواه مسلم وأخرج البخاري الجملة الأخيرة منه] - [صحيح مسلم: 2003]
المزيــد ...
Lati ọdọ ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira ọti ni, ati pe gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira eewọ ni, ati pe ẹni ti o ba mu ọti ni aye ti o wa ku ni ẹni ti o kúndùn rẹ ti ko tuuba, ko nii mu un ni ọjọ ikẹyin».
[O ni alaafia] - - [Sọhiihu ti Muslim - 2003]
Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣe alaye pe dajudaju gbogbo nkan ti o ba ti le mu laakaye lọ ni ọti ti n pa eeyan, yala o jẹ mímu tabi jijẹ tabi fifin simu tabi eyi ti o yato si i, ati pe dajudaju gbogbo nkan ti o le muni maa hunrira ti O si maa pa laakaye ni Ọlọhun Ọba ti O biyi ti O gbọnngbọn ti ṣe e ni eewọ ti O si tun kọ kuro nibẹ, kekere rẹ ni ati pipọ rẹ, Ati pe gbogbo ẹni ti o ba mu èyíkéyìí ninu awọn iran nkan ti o máa ń muni hunrira, ti o tun wa dunni mọ mimu un ti ko si tun tuuba ninu rẹ ti o fi ku; onítọ̀hún ti lẹtọọ si Iya Ọlọhun pẹlu ṣiṣe mimu un ni eewọ fun un ninu al-jannah.