+ -

عن أنس رضي الله عنه أن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«جَاهِدُوا المشركين بأموالكم وأنفسكم وألسنتكم».

[صحيح] - [رواه أبو داود والنسائي وأحمد] - [سنن أبي داود: 2504]
المزيــد ...

Láti ọdọ Anas - ki Ọlọhun yọnu si i - dájúdájú Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pé:
"E ṣe ìgbìyànjú igbogunti awon olusẹbọ pẹlu Ọlọhun pẹlu owo yin ati èmi yín àti ahán yin".

[O ni alaafia] - [رواه أبو داود والنسائي وأحمد] - [Sunanu ti Abu Daud - 2504]

Àlàyé

Anọbi (kí ikẹ Ọlọhun ati ọlá Rẹ máa bà) pa wà lasẹ lati gbógun ti alaigbagbọ, ki a sì ná ìgbìyànjú láti dájú kọ won pẹlu gbogbo ọnà tí a ni ìkápá le lórí nítorí kì gbólóhùn ati ọrọ Ọlọhun le wa loke, nínú ìgbìyànjú náà ni:
Alakọkọ: nina owó àti dukia lati fi gbógun ti won, bí rírà nkan ijagun, ati ìnáwó lórí awon jagunjagun ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹlẹkeji: ki a jàdé pẹlu emi ati ará lati lọ pàdé won ati lati da won pàdà.
Ẹlèkẹta: pẹlu pípé won síbi ẹṣin Islam yi pẹlú ahán, ati ifi idi ọrọ ati ẹri rinlẹ fún won ati ijagbe mọ won ati ìfun won lèsi.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. iseni lojúkòkòrò lati gbógun ti olusẹbọ pẹlú ẹmi ati owó àti ahán, ni ibámu sí Olukaluku bá ṣè ni agbára àti ìkápá mọ, ati pé dájúdájú ìjagun sójú ọnà Ọlọhun kii ṣe fífi ẹmi jà nikan ni.
  2. Ipani lasẹ lati jagun jẹ ọranyan, o le jẹ ọranyan ojúlówó fún gbogbo musulumi, o sí le jẹ òranyàn tito.
  3. Olohun se ogun jija ni òfin ẹṣin nítorí àwọn nkán nkán ninu rẹ ni:
  4. Alakọkọ: Gbigbogun ti ise ẹbọ ati awon olusẹbọ, nítorípé Ọlọhun Ọba ko ni gba ise ẹbọ laye laye.
  5. Ẹlẹkeji: Mímú awọn iṣoro àti wàhálà ti nkọ di ojú ọnà ìpepé sí ojú ònà Ọlọhun kúrò.
  6. Ẹlèkẹta: Didaabo bó ìgbàgbọ àti adisọkan nibi gbogbo nkan ti o ba yàtọ sí.
  7. Ẹlẹkẹrin : Didaabo bó awon musulumi ati awọn ilu won, Omoluabi won ati dukia (awon nkan ini won).
Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية المقدونية الخميرية الماراثية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Àlékún