عن عبد الله بن عمرو رضي الله عنهما عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ قَتَلَ مُعَاهَدًا لَمْ يَرَحْ رَائِحَةَ الْجَنَّةِ، وَإِنَّ رِيحَهَا تُوجَدُ مِنْ مَسِيرَةِ أَرْبَعِينَ عَامًا».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 3166]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amr- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Ẹni ti o ba pa ẹni a gba adehun lọwọ rẹ ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ wọn maa n gbọ́ ọ lati ijinna ogoji ọdun”.
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3166]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé adehun iya ti o le koko to wa lori pe dajudaju ẹni ti o ba pa ẹni ti a gba adehun lọwọ rẹ- oun ni ẹni ti o wọ ilẹ̀ Isilaamu ninu awọn alaigbagbọ pẹlu adehun ati ifọkanbalẹ- pe ẹni naa ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ maa jẹ ijiina irin ogoji ọdun.