عن أبي هريرة رضي الله عنه قال:
لَعَنَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ الرَّاشِيَ وَالْمُرْتَشِيَ فِي الْحُكْمِ.
[صحيح] - [رواه الترمذي وأحمد] - [سنن الترمذي: 1336]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹ́ ibi lé ẹni ti n san abẹtẹlẹ ati ẹni ti n gba a nibi idajọ (igbẹjọ).
[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 1336]
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹ ibi ilejina si ikẹ Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn le ẹni ti n san abẹtẹlẹ ati ẹni ti n gba a.
Ati pe ninu rẹ naa ni eyiti wọn maa n fun awọn adajọ lati le jẹ ki wọn o ṣe abosi nínú ẹjọ ti wọn n da; ki ẹni ti o fun un le baa de ibi nkan ti o n fẹ lai ni ẹtọ si i.