عَنْ مَعْدَانَ بْنِ أَبِي طَلْحَةَ الْيَعْمَرِيُّ قَالَ:
لَقِيتُ ثَوْبَانَ مَوْلَى رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَقُلْتُ: أَخْبِرْنِي بِعَمَلٍ أَعْمَلُهُ يُدْخِلُنِي اللهُ بِهِ الْجَنَّةَ؟ أَوْ قَالَ قُلْتُ: بِأَحَبِّ الْأَعْمَالِ إِلَى اللهِ، فَسَكَتَ. ثُمَّ سَأَلْتُهُ فَسَكَتَ. ثُمَّ سَأَلْتُهُ الثَّالِثَةَ فَقَالَ: سَأَلْتُ عَنْ ذَلِكَ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَقَالَ: «عَلَيْكَ بِكَثْرَةِ السُّجُودِ لِلَّهِ، فَإِنَّكَ لَا تَسْجُدُ لِلَّهِ سَجْدَةً، إِلَّا رَفَعَكَ اللهُ بِهَا دَرَجَةً، وَحَطَّ عَنْكَ بِهَا خَطِيئَةً» قَالَ مَعْدَانُ: ثُمَّ لَقِيتُ أَبَا الدَّرْدَاءِ فَسَأَلْتُهُ فَقَالَ لِي: مِثْلَ مَا قَالَ لِي: ثَوْبَانُ.
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 488]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ma'daan ọmọ Abu Tolha Al-Ya'mariy o sọ pe:
Mo pade Thaobaan ẹru ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mo wa sọ pe: Fun mi ni iro nipa iṣẹ kan ti mo ba n ṣe e Ọlọhun maa fi mu mi wọnu alujanna? Tabi o sọ pe mo sọ pé: pẹlu eyi ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ ninu awọn iṣẹ, o ba dakẹ. Lẹ́yìn naa mo bi i leere ni o ba dakẹ. Lẹ́yìn naa mo bi i leere ni ẹẹketa, o wa sọ pe: Mo beere nipa ìyẹn lọwọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Fiforikanlẹ fun Ọlọhun lọpọlọpọ jẹ dandan fun ẹ, dajudaju o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ ẹẹkan, afi ki Ọlọhun fi gbé ẹ ga nipo, ki O si fi ba ẹ pa ẹṣẹ rẹ" Ma'daan sọ pe: Lẹyin naa mo pade Abu Dardaa mo si bi i leere, o si sọ fun mi: Iru nnkan ti Thaobaan sọ fun mi.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 488]
Wọn beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa iṣẹ ti o maa jẹ okunfa fun wiwọnu alujanna tabi nipa eyi ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ?
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun olubeere pe: Dunni mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iforikanlẹ nibi irun, o ko nii forikanlẹ fun Ọlọhun ni iforikanlẹ kan afi ki O fi gbe ẹ ga nípò, ki O si fi i ṣe aforijin fun ẹ.