عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ:
كَانَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَسِيرُ فِي طَرِيقِ مَكَّةَ، فَمَرَّ عَلَى جَبَلٍ يُقَالُ لَهُ جُمْدَانُ، فَقَالَ: «سِيرُوا هَذَا جُمْدَانُ، سَبَقَ الْمُفَرِّدُونَ» قَالُوا: وَمَا الْمُفَرِّدُونَ يَا رَسُولَ اللهِ؟ قَالَ: «الذَّاكِرُونَ اللهَ كَثِيرًا وَالذَّاكِرَاتُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2676]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n rin loju ọna Makkah, ni o ba kọjá nibi oke kan ti wọn n pe e ni Jumdaan, o sọ pe: "Ẹ maa rin lọ, Jumdaan nìyí, àwọn MUFARRIDUUN ti ṣíwájú" wọn sọ pe: Awọn wo ni MUFARRIDUUN irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: Awọn ni àwọn oluranti Ọlọhun lọkunrin lọpọlọpọ ati awọn oluranti Ọlọhun lobinrin".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2676]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé ipo awọn oluranti Ọlọhun lọpọlọpọ, pe wọn ti dá wà wọ́n si ti ṣáájú àwọn ti wọn yàtọ̀ si wọn pẹlu pe ọwọ wọn tẹ awọn ipo ti o ga julọ ninu alujanna onidẹra, o wa fi wọn we oke Jumdaan ti o da wa laarin awọn oke yókù.