عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ قَالَ: سُبْحَانَ اللهِ وَبِحَمْدِهِ، فِي يَوْمٍ مِائَةَ مَرَّةٍ، حُطَّتْ خَطَايَاهُ وَإِنْ كَانَتْ مِثْلَ زَبَدِ الْبَحْرِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6405]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni ti o ba sọ pe: SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa àwọn ẹṣẹ rẹ rẹ kódà ki o da gẹgẹ bii ìfòfó agbami odò”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6405]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí o ba sọ pe SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa ẹṣẹ rẹ rẹ, wọn si maa fi ori jin in, kódà ki ẹṣẹ rẹ pọ bii ifofo funfun ti o maa n wa lókè agbami odò nigba ti ìgbì rẹ ba n bì ati ti o ba ru sókè