عن عُمر بن أبي سلمة رضي الله عنه قال:
كُنْتُ غُلَامًا فِي حَجْرِ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، وَكَانَتْ يَدِي تَطِيشُ فِي الصَّحْفَةِ، فَقَالَ لِي رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «يَا غُلَامُ، سَمِّ اللهَ، وَكُلْ بِيَمِينِكَ، وَكُلْ مِمَّا يَلِيكَ» فَمَا زَالَتْ تِلْكَ طِعْمَتِي بَعْدُ.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 5376]
المزيــد ...
Lati ọdọ Umar ọmọ Abu Salama- ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
Mo jẹ ọmọdekunrin ni abẹ itọju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati pe ọwọ mi o si duro si oju kan ninu abọ, ni Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun mi pé: «Irẹ ọmọdekunrin yii, darukọ Ọlọhun, ki o si jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ki o si tun jẹ ninu nkan ti o sunmọ ọ»
Ìyẹn o wa yẹ ni ìṣesí ounjẹ mii lẹyin igba naa.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5376]
Umar ọmọ Abu Salamah- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -, ọmọ iyawo anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti n ṣe ummu salamah - ki Ọlọhun yọnu si i - o si wa ni abẹ itọju rẹ ati amojuto rẹ -, n sọ pé òun jẹ ẹni ti o maa n gbe ọwọ rẹ kaakiri ẹgbẹẹgbẹ abọ ni asiko ounjẹ, nitori naa Anabi - kí ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa kọ ọ ni awọn ẹkọ mẹta ninu awọn ẹkọ jijẹ:
Alakọkọọ rẹ ni: Gbólóhùn "BismilLah" ni ibẹrẹ ounjẹ.
Ati pe ẹlẹẹkeji ni: jíjẹ ounjẹ pẹlu ọwọ ọtun.
Ati pe ẹlẹẹkẹta rẹ ni: Jijẹ nibi ẹgbẹ ti o ba sunmọ ọn ninu oúnjẹ.