عن ابن عمر رضي الله عنهما أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«إِذَا أَكَلَ أَحَدُكُمْ فَلْيَأْكُلْ بِيَمِينِهِ، وَإِذَا شَرِبَ فَلْيَشْرَبْ بِيَمِينِهِ، فَإِنَّ الشَّيْطَانَ يَأْكُلُ بِشِمَالِهِ، وَيَشْرَبُ بِشِمَالِهِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2020]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
“Ti ẹnikẹni ninu yẹn ba fẹ jẹun ki o yaa jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ti o ba si fẹ mu ki o yaa mu pẹlu ọwọ ọtun rẹ, dajudaju Shaitan maa n jẹun pẹlu ọwọ osi rẹ, o si maa n mu pẹlu ọwọ osi rẹ”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2020]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ pe ki Musulumi maa jẹ ki o si maa mu pẹlu ọwọ rẹ ọtun, o si kọ kuro nibi jijẹ ati mimu pẹlu ọwọ osi; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pe Shaitan maa n jẹ o si maa n mu pẹlu rẹ.