+ -

عَنِ ‌ابْنِ عَبَّاسٍ رَضِيَ اللهُ عَنْهُمَا قَالَ:
كَانَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَليهِ وَسَلَّمَ لا يَعْرِفُ فَصْلَ السُّورةِ حَتَّى تَنْزِلَ عَليْهِ {بِسْمِ اللَّهِ الرَّحْمَنِ الرَّحِيمِ}.

[صحيح] - [رواه أبو داود]
المزيــد ...

Lati ọdọ Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe:
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii mọ gígé àsopọ̀ suura titi ti {BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM} fi maa sọkalẹ.

O ni alaafia - Abu Daud ni o gba a wa

Àlàyé

Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- n ṣàlàyé pe àwọn suura Kuraani Alapọn-ọnle maa n sọ̀kalẹ̀ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko si nii mọ ibi ti asopọ rẹ ti ge ati òpin rẹ, titi ti "c2">“BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM” fi maa sọ̀kalẹ̀ fun un, igba naa ni o to maa mọ pe suura ti o ṣáájú ti parí, oun si ni ibẹrẹ suura tuntun.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. A maa n fi BASMALAH ṣe opinya laarin awọn suura ni, ayafi láàrin suuratul Anfaal ati suurat At-Taobah.
Àlékún