+ -

عَنْ ‌أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«أَيُحِبُّ أَحَدُكُمْ إِذَا رَجَعَ إِلَى أَهْلِهِ أَنْ يَجِدَ فِيهِ ثَلَاثَ خَلِفَاتٍ عِظَامٍ سِمَانٍ؟» قُلْنَا: نَعَمْ. قَالَ: «فَثَلَاثُ آيَاتٍ يَقْرَأُ بِهِنَّ أَحَدُكُمْ فِي صَلَاتِهِ خَيْرٌ لَهُ مِنْ ثَلَاثِ خَلِفَاتٍ عِظَامٍ سِمَانٍ».

[صحيح] - [رواه مسلم]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"c2">“Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni nínú yín yóò fẹ́, nígbà tí ó bá padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀, láti rí ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra ni ọdọ wọn?” A sọ pé: Bẹ́ẹ̀ ni. Ó sọ pé: "c2">“Àwọn aaya mẹ́ta tí ọ̀kan nínú yín máa ń ka lori irun rẹ ni oore fun un ju ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra lọ”
.
O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe ẹ̀san kika aaya mẹ́ta lori irun; o ni oore ju ki èèyàn o ri ràkúnmí aboyún mẹ́ta ti wọn tobi ti wọn sanra ni ilé rẹ lọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Àlàyé ọla ti n bẹ fun kika Kuraani ni orí ìrun.
  2. Awọn iṣẹ rere ni oore, wọn ṣi tun maa ṣẹku titi láéláé ju igbadun ayé ti o maa tán lọ.
  3. Ọla yii kò mọ lori kika aaya mẹta nìkan, gbogbo ìgbà ti ẹni tí n kirun ba ti n ṣe alekun nibi kika àwọn aaya nibi irun rẹ ni ẹsan rẹ maa loore fun un ju iye onka wọn ninu ràkúnmí aboyún lọ.