عن شداد بن أوس رضي الله عنه قال: ثِنْتَانِ حَفِظْتُهُمَا عَنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«إِنَّ اللهَ كَتَبَ الْإِحْسَانَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ، فَإِذَا قَتَلْتُمْ فَأَحْسِنُوا الْقِتْلَةَ، وَإِذَا ذَبَحْتُمْ فَأَحْسِنُوا الذَّبْحَ، وَلْيُحِدَّ أَحَدُكُمْ شَفْرَتَهُ، فَلْيُرِحْ ذَبِيحَتَهُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1955]
المزيــد ...
Lati ọdọ Shaddaad ọmọ Aos- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo há nǹkan méjì lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o sọ pe:
“Dájúdájú Ọlọhun ti ṣe dáadáa ni ọranyan nibi gbogbo nǹkan, ti ẹ ba ti fẹ pa nǹkan ki ẹ pa a dáadáa, ti ẹ ba ti fẹ du nǹkan, ki ẹ du u dáadáa, ki ẹni kọọkan yin pọ́n ọ̀bẹ rẹ ki ó mú, ki o si tètè ko ìsinmi ba nǹkan ti o fẹ dú”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1955]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe daadaa ni ọranyan le wa lori nibi gbogbo nǹkan. Dáadáa ni: Ìpayà Ọlọhun ni gbogbo ìgbà, níbi ìjọsìn fun Un, ati ṣíṣe oore, ati ki èèyàn má ṣe àwọn ẹ̀dá ni suta, ninu ìyẹn naa ni ṣíṣe dáadáa nibi pípa ati didu.
Ṣíṣe dáadáa nibi pipa nigba ti a ba fẹ gba ẹsan: Pẹ̀lú sisẹṣa ọna ti o rọrun ju ti o si yára ju lati gba ẹ̀mí ẹni ti a fẹ pa.
Ṣíṣe dáadáa nibi dídú nígbà tí a ba n dú nǹkan: Pẹ̀lú ṣíṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú ẹran-ọ̀sìn pẹlu pípọ́n irinṣẹ naa, ki a si ma pọ́n ọn ni iwájú nǹkan ti a fẹ du ti o si n wò ó, ki a si ma dú u ni ibi tí ẹran-ọ̀sìn mìíràn wa ti o n wò ó.