+ -

عَنْ أَبِي مُوسَى رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«إِنَّ اللهَ عَزَّ وَجَلَّ يَبْسُطُ يَدَهُ بِاللَّيْلِ لِيَتُوبَ مُسِيءُ النَّهَارِ، وَيَبْسُطُ يَدَهُ بِالنَّهَارِ لِيَتُوبَ مُسِيءُ اللَّيْلِ، حَتَّى تَطْلُعَ الشَّمْسُ مِنْ مَغْرِبِهَا».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2759]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Mūsa - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn maa n tẹ ọwọ Rẹ ni oru lati gba tuuba ẹni ti o ba da ẹṣẹ ni ọsan, O si tun maa n tẹ ọwọ Rẹ ni ọsan lati gba tuuba ẹni ti o da ẹṣẹ ni oru titi oorun o fi yọ ni ibi ti o ti maa n wọ».

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2759]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n funni ni iro pe: Dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n gba tituuba awọn ẹru rẹ, ti ẹru ba da ẹṣẹ kan ni ọsan ti o si tuuba ni oru Ọlọhun o gba tuuba rẹ, ti o ba si da ẹsẹ ni oru ti o wa tuuba ni ọsan Ọlọhun a gba tuuba rẹ, Ọba ti mimọ n bẹ fun Un maa n tẹ ọwọ Rẹ fun tuuba ni ti ìdùnnú si i ati gbigba a, ati pe ilẹkun tituuba o yẹ ni nkan ti wọn maa ṣi silẹ titi oorun o fi yọ nibi ti o ti n wọ ni ti ikede titan ayé, ti o ba ti wa yọ dajudaju ilẹkun tituuba ti di titi niyẹn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Gbigba tuuba n tẹ síwájú lopin ìgbà tí ilẹkun rẹ ba si wa ni ṣiṣi silẹ, ati pe wọn maa ti ilẹkun rẹ pẹlu yiyọ oorun ni ibuwọ rẹ, ati pe ki ọmọniyan o tuuba siwaju ipọka iku, oun naa ni ki ẹmi de ọ̀nà ọ̀fun.
  2. Ki eeyan ma sọ ìrètí nu torí ẹṣẹ, dajudaju amojukuro Ọlọhun ti mimọ n bẹ fun Un ati ikẹ Rẹ nkan ti o gbaaye ni, ati pe ilẹkun tituuba wa ni ṣiṣi silẹ.
  3. Awọn majẹmu tituuba: Akọkọ: Jijawọ kuro ninu ẹṣẹ, ẹlẹẹkeji: kika abamọ l'ori ṣiṣe é, ẹlẹẹkẹta: Ìpinnu lati ma pada si ibẹ mọ láéláé, eyi ni nibi awọn ẹtọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, amọ ti o ba wa sokọ mọ ẹtọ awọn ẹru, nigba naa wọn ṣe e ni majẹmu tituuba ki o da ẹtọ yẹn pada si ọdọ ẹni ti o ni i, tabi ki ẹni ti o ni ẹtọ yẹn o yaafi rẹ.