عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«لَأَنْ أَقُولَ: سُبْحَانَ اللهِ، وَالْحَمْدُ لِلهِ، وَلَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَاللهُ أَكْبَرُ، أَحَبُّ إِلَيَّ مِمَّا طَلَعَتْ عَلَيْهِ الشَّمْسُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2695]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe:
“Ki n sọ pe: Subhaanallah, wal hamdulillah, wa laa ilaaha illallohu, wallohu akbar, jẹ nnkan ti mọ nifẹẹ sí ju nnkan ti oorun ran le lori lọ”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2695]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju riranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu awọn gbolohun ti wọn tobi yii loore ju aye ati nnkan ti o wa ninu rẹ lọ, awọn naa ni:
“Subhaanallah”: Afọmọ ni fun Ọlọhun kuro nibi awọn adinku.
“Alhamdulillah”: Ẹyin ni fun Un pẹlu awọn iroyin pipe pẹlu nini ifẹ Rẹ ati gbigbe E tobi.
“Laa ilaaha illallohu”: ko si ẹni ti a le maa jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Ọlọhun.
“Allahu Akbar”: Ẹni ti O tobi julọ ti O gbọnngbọn ju gbogbo nnkan lọ.