عن أبي هريرة رضي الله عنه: أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«لَا تَجْعَلُوا بُيُوتَكُمْ مَقَابِرَ، إِنَّ الشَّيْطَانَ يَنْفِرُ مِنَ الْبَيْتِ الَّذِي تُقْرَأُ فِيهِ سُورَةُ الْبَقَرَةِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 780]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i– dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe:
“Ẹ ko gbọdọ sọ awọn ile yin di awọn iboji, dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 780]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi ki a ma maa kirun ni ile, ti yoo fi wa da gẹgẹ bii awọn iboji ti wọn ko kii n kirun nibẹ.
Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe pipọ ni ijọsin ni ohun ti a fẹ ati kiki irun akigbọrẹ ninu ile.
  2. Irun kiki ko lẹtọọ ni awọn iboji; nitori pe o jẹ ọna kan ninu awọn ọna ti wọn maa n gba lati ṣe ẹbọ ati kikọja aala nipa awọn ti wọn wa nibẹ, yatọ si irun ti a maa n ki si oku lara.
  3. Kikọ kuro nibi kiki irun nibi awọn sàréè fi ẹsẹ rinlẹ lọdọ awọn saabe, nitori idi eyi ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi kọ lati jẹ ki awọn ile da gẹgẹ bii awọn iboji ti wọn ko kii n kirun nibẹ.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (62)