عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«لَا تَدْخُلُونَ الْجَنَّةَ حَتَّى تُؤْمِنُوا، وَلَا تُؤْمِنُوا حَتَّى تَحَابُّوا، أَوَلَا أَدُلُّكُمْ عَلَى شَيْءٍ إِذَا فَعَلْتُمُوهُ تَحَابَبْتُمْ؟ أَفْشُوا السَّلَامَ بَيْنَكُمْ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 54]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa gbagbọ, ati pe e ko lee gbagbọ titi ti ẹ fi máa nífẹ̀ẹ́ ara yin, ẹ wa jẹ ki n juwe yin si nkankan ti o jẹ pe ti ẹ ba ṣe e ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yin? Ẹ maa tan salamọ ka laarin ara yin».
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 54]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ẹnikankan o lee wọ alujanna ayaafi muumini, ati pe igbagbọ o lee pe ati pe ìṣesí awujọ musulumi o lee daa titi ti wọn o fi nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa juwe lọ sibi eyiti o lọla julọ ninu awọn alamọri eyiti o ṣe pe pẹlu rẹ ni ifẹ fi maa n kari, oun naa ni fifọn salamọ ka laarin awọn musulumi, eleyii ti Ọlọhun ṣe ni kiki fun awọn ẹru Rẹ.