عَنْ عُقْبَةَ بْنِ عَامِرٍ رضي الله عنه قَالَ:
قُلْتُ: يَا رَسُولَ اللهِ مَا النَّجَاةُ؟ قَالَ: «امْلِكْ عَلَيْكَ لِسَانَكَ، وَلْيَسَعْكَ بَيْتُكَ، وَابْكِ عَلَى خَطِيئَتِكَ».
[صحيح] - [رواه الترمذي وأحمد] - [سنن الترمذي: 2406]
المزيــد ...
Lati ọdọ 'Uqbatu ọmọ 'Aamir - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé:
"Mo sọ pé: Mope irẹ ojisẹ Ọlọhun kini ìgbàlà? O sọ pé: “ko ahán rẹ ni ijanu, jẹ kí ilé rẹ gba ọ laaye, ki o si máa sunkún lori awọn àsise rẹ".
[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2406]
'Uqbatu ọmọ 'Aamir ki Ọlọhun yọnu si beere lọwọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nipa Òkùnfà ti olugbàgbọ òdodo yóò fi ri àkóyọ láyé ati lọrun?
Ni ojisẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Rẹ máa ba) wa sọ pé: nkan mẹta di ọwọ rẹ:
Èkíní: ṣọ ahán rẹ kúrò níbi nkan ti kosi oore nibẹ, ati kúrò níbi gbogbo ọrọ aburu, ma se sọ ọrọ kan afi ko jẹ ọrọ daada.
Ikeji: fìdí rẹ mọ ile rẹ ki o lè máa ṣe ìjọsìn fún Ọlọhun ni kọkọ (nigbati o ba da wa), gbaju mọ itẹle aṣẹ Ọlọhun Ọba to gbọngbọn ti o tun ga jùlọ, dáwà ninu ile rẹ lati sa fún wahala.
Ikẹta: Máa sunkún ki o si máa ṣe àbámọ ki o si tuuba (tọrọ aforinjin ati iyọwọ kúrò) ni bi awọn ẹsẹ ti o ti ṣe kọja.