عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«مَا مِنْ قَوْمٍ يَقُومُونَ مِنْ مَجْلِسٍ لَا يَذْكُرُونَ اللَّهَ فِيهِ إِلَّا قَامُوا عَنْ مِثْلِ جِيفَةِ حِمَارٍ، وَكَانَ لَهُمْ حَسْرَةً».
[صحيح] - [رواه أبو داود] - [سنن أبي داود: 4855]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayrah - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) sọ pe:
"Kòsí ijọkan ti wọn yóò dide láti ibi jokolẹ kan láì dárúkọ Ọlọhun níbẹ ayaafi ki wọn didi bi àpèjúwe okunbete Kẹtẹkẹtẹ, bẹẹ ni yóò tún jẹ ìbànújẹ́ fún wọn.
[O ni alaafia] - [Abu Daud ni o gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 4855]
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro pe kò ní sí awọn apapọ eniyan kan tí wọn joko sí ààyè ijoko kan ti wọn wa dìde láì dárúkọ Ọlọhun nibẹ àyàafi ki wọn dide gẹgẹ bí àwọn ti wọn ko jọ lórí òku kẹtẹkẹtẹ ni ori akitan ati aye oorùn; eleyi ri bẹ nítorípé wọn ṣe airoju kuro nibi ìrántí Ọlọhun, ijoko naa yoo jẹ ìbànújẹ́ fun wọn lọjọ igbende, yoo si jẹ abuku ati àbámọ ti yóò maa wà pẹlu wọn.