Ìsọ̀rí ti ẹka

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn hadiisi

1. Ẹnikẹni ti o ba ṣe Hajj nitori ti Ọlọhun, tí kò ba obinrin lopọ, tí kò sì rú ofin Ọlọhun, onitọhun yoo pada sile gẹgẹ bi ọjọ ti iya rẹ̀ bi i
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
2. “Njẹ emi ko wa ni fun yin ni iro nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ ńlá bi?” - 6 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
3. “Bí ọkùnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, kí ó sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
4. “Awọn ẹṣẹ nlanla ni: Mimu orogun pẹlu Ọlọhun, ṣiṣẹ baba ati ìyá, pipa ẹmi, ati bibura lori irọ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
5. A ṣadehun fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori gbigbọ ati itẹle nigba ilekoko ati irọrun, ati nibi nnkan ti a fẹ ati nnkan ti a kọ, ati lori iwa imọtaraẹni nikan - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
6. “ko si irun pẹlu ikalẹ ounjẹ, tabi nigba ti igbẹ ati itọ ba n gbọ̀n ọ́n” - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
7. Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ pe: Dakẹ, ni ọjọ jimọ, ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, o ti sọ ọrọ kọrọ - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
8. Oluran awọn opo ati alaini lọwọ, da gẹgẹ bii olugbinyanju soju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n fi oru rẹ dide ti o si n fi ọsan rẹ gba awẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
9. “Adamọ marun-un lo jẹ: Dida abẹ ati fifa irun abẹ ati gige tubọmu ati gige awọn èékánná ati fifa irun abiya”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
10. Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa mi ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ko wa ninu awọn ara ina - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
11. “Ẹ ge awọn tubọmu ki ẹ si da awọn irungbọn si”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
12. Ẹni ti o ba ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yii lẹyin naa o wa ki rakah meji ti ko ba ẹmi rẹ sọrọ nibi mejeeji, Ọlọhun yoo fori nnkan ti o ṣíwájú ninu ẹṣẹ rẹ jin in - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
13. Egbe Ọlọhun ko lọ maa ba awọn Juu ati Nasara, ti wọn mu awọn saare awọn Anabi wọn ni mọsalasi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
14. “Ẹ yẹra fún awọn nkan meje tí n pani run - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
15. “Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
16. Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀ - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
17. Dajudaju emi n bọpabọsẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pe ki n ní ọrẹ aayo kan laarin yin, nitori pe Ọlọhun Ọba Aleke ọla ti mú mi ní ọrẹ aayo gẹgẹ bi O ti mu Ibrahim ni ọrẹ aayo
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
18. “Ẹ má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ sì má sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dajudaju asalatu yín ó kàn mi lara lati ibikibi ti ẹ ba wa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
19. Dajudaju Ọlọhun maa n jowu, ati pe dajudaju olugbagbọ naa maa n jowu, owu jijẹ Ọlọhun ni ki olugbagbọ maa ṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ fun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
20. Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣẹbọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
21. Dajudaju irun ti o wuwo ju fun awọn munaafiki ni irun Ishai ati Asunbaa, ka ni wọn mọ nkan ti n bẹ ninu rẹ - ni ẹsan – ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ ni irakoro - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
22. Dajudaju ninu awọn eniyan ti o buru julọ ni ẹni ti ọjọ igbedide ba ba ti wọn si wa ni alààyè, ati ẹni ti o ba mu awọn saare ni mọsalasi - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
23. Dajudaju nnkan ti mo n bẹru julọ nipa yin ni ẹbọ kekere" wọn sọ pe: Ki ni ẹbọ kekere irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: "Ṣekarimi ni - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
24. Iwọ yoo lọ sí ọdọ awọn eniyan kan ti wọ́n jẹ́ oni-tira sánmọ̀, tí o bá dé ọdọ wọn, pẹ̀ wọn kí o sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
25. Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀ - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
26. Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
27. Ọlọhun a mu u wọ al-jannah lori èyíkéyìí iṣẹ ti o ba wa lori rẹ - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
28. Ẹniti ó bá pade Ọlọhun ni ẹniti kò mú orogun kankan pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Alujanna, ṣugbọn ẹniti ó bá pade Rẹ̀ ni ẹniti ó mú orogun pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Ina
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
29. Ẹni ti o ba ku ti o si n pe akẹgbẹ kan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun, o maa wọ ina
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
30. Awọn alakatakiti ti parun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
31. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dámilójú pé oun yóò ṣọ́ nkan tí n bẹ láàrín eegun ẹnu rẹ méjèèjì àti nkan tí n bẹ láàrín ẹsẹ̀ rẹ méjèèjì, èmi yóò fi dá a lójú pé yoo wọ Alujanna
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
32. Awọn adari kan maa jẹ, ẹ maa mọ ẹ si maa ṣe atako, ẹni ti o ba mọ, o ti bọ, ẹni ti o ba ṣe atako, o ti la, sugbọn ẹni ti o ba yọnu ti o si tẹle
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
33. Ọlọhun o nii gba irun ẹnikẹni ninu yin ti o ba ti ni ẹgbin lara titi ti yio fi ṣe aluwala - 6 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
34. Tí ẹrú Ọlọhun kan bá ṣàìsàn tabi ó rin irin-ajo, wọn yoo kọ laada silẹ fun un fún iṣẹ tí n ṣe nigba tí ó wà nílé tó sì lalaafia - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
35. Eyi tó lọ́lá jùlọ ninu awọn iranti Ọlọhun ni gbolohun: LAA ILAAHA ILLALLOOH, eyi tó sì lọ́lá jùlọ ninu awọn adura ni gbolohun: ALHAMDULILLAH
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
36. Alujanna súnmọ́ ìkọ̀ọ̀kan nínú yín ju okùn bàtà rẹ̀ lọ, Iná naa sì rí bẹ́ẹ̀
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
37. Pákò jẹ́ imọtoto fun ẹnu, ó sì jẹ́ okunfa iyọnu Oluwa - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
38. Awọn ìrun wakati maraarun, Irun Jimọ sí Jimọ, Ramadan sí Ramadan, ó máa n pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí n bẹ laarin wọn rẹ́ ni, tí eniyan bá ti jìnnà sí awọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá - 8 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
39. Ẹ jẹ́ iṣẹ mi koda bo ṣe pẹlu aayah kan, kí ẹ sì sọrọ nipa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kò sí aburu nibẹ, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ parọ́ mọ́ mi, kí onitọhun yaa tètè mú ibùjókòó rẹ̀ nínú Iná - 8 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
40. Nnkan kan ko nii ṣẹlẹ̀ si Musulumi ninu wahala ati aisan ati ironu ati ibanujẹ ati suta ati ironu ati ki ẹgun gun un afi ki Ọlọhun ba a fi pa awọn aṣiṣe rẹ rẹ - 6 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
41. Wọ́n fi awọn adùn tí eniyan n fẹ́ nifẹkufẹẹ rọkirika Iná ọ̀run, wọ́n sì fi awọn nkan tí ọkàn eniyan koriira rẹ̀ rọkirika Alujanna
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
42. Etọ Musulumi lori Musulumi miiran márùn-ún ni: Dídá salamọ pada, bibẹ alaarẹ wò, titẹle ìsìnkú, didahun ipepe, ṣiṣadura fun ẹniti ó bá sín
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
43. Ikẹ Ọlọhun kó maa bá ọkunrin kan tí ó maa n ṣe ìrọ̀rùn fúnni nígbà ti ó bá tajà, ati nigba ti ó bá rajà, ati nigba ti ó bá fẹ́ gba gbèsè
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
44. Ọkùnrin kan wà tó máa ń yá àwọn eniyan ní owo, ó sì máa ń sọ fún ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ pé: Ti o bá de ọdọ alaini, ki o ṣamojukuro fun un, bóyá Ọlọ́hun yoo ṣamojukuro fún awa naa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
45. Kii ṣe ẹniti n fi dáadáa ṣẹ̀san dáadáa ni ó pé perepere nibi siso okùn-ẹbi, ṣugbọn oluso okùn-ẹbi gangan ni ẹniti ó jẹ́ pé nigba ti awọn eniyan bá já okùn-ẹbi rẹ̀ dànù, ó maa n so o padà - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
46. “Ẹni ti o ba lọ onigbese lára, tabi ti o ba a din in ku tabi ki o ni ki o ma san an mọ́, Ọlọhun maa fi i sábẹ́ ibòji Ìtẹ́-ọlá Rẹ̀ ni Ọjọ́ Àjíǹde, ni ọjọ́ ti ko nii si ibòji kankan àyàfi ibòji Rẹ̀”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
47. “Ẹni tí ó bá gba aawẹ Ramadan ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹsẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
48. “Ẹni tí ó bá dìde ni oru Laelatul Kọdri ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹṣẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
49. “Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fún, O maa fi àdánwò kàn án”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
50. “Ti Mùsùlùmí méjì ba pàdé ara wọn pẹ̀lú idà, ati ẹni ti o pa eeyan ati ẹni tí wọ́n pa, wọn jọ maa wọ iná ni
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
51. “Ẹsin ìmọ̀ràn ni
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
52. “Dajudaju nǹkan ẹtọ fi ojú hàn, dájúdájú nǹkan eewọ naa fi ojú hàn - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
53. “Dájúdájú Ọlọhun ti ṣe dáadáa ni ọranyan nibi gbogbo nǹkan - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
54. Dájúdájú Ọlọhun kọ daadaa ati aburu, lẹyin naa O ṣalaye ìyẹn, ẹni tí ó bá gbèrò dáadáa, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pé, ti o ba wa gbero rẹ, ti o wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa mẹ́wàá titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ̀, ẹni ti o ba gbèrò aburu, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pe, ti o ba wa gbero rẹ ti o si ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
55. “Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati dúkìá yin, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn yin ati iṣẹ yin” - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
56. Àwọn iṣẹ pẹ̀lú àwọn àníyàn ni, o maa jẹ ti ọmọniyan kọ̀ọ̀kan ohun ti o ba gba lero - 6 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
57. Isilaamu ni ki o jẹ́rìí pe ko si ẹni tí ìjọsìn tọ si lododo ayafi Ọlọhun, ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Rẹ, ki o maa gbe ìrun dúró, ki o maa yọ sàká, ki o maa gba aawẹ Ramadan, ki o maa ṣe hajj ti o ba ni ikapa ọ̀nà lọ si ibẹ - 32 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
58. Ma ṣe maa binu - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
59. “Ma ṣe maa ni eeyan lara, ma ṣe maa gba ẹsan ìnira, ẹni tí ó bá fi ara ni èèyàn, Ọlọhun yoo fi ara ni in, ẹni tí ó bá ko ìpalára ba èèyàn, Ọlọhun yoo ko ìpalára ba a” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
60. “Ti o ba jẹ pe ẹ n gbẹkẹle Ọlọhun gẹgẹ bi o ti yẹ ki ẹ gbẹkẹle E ni, Oun iba pese fun yin gẹ́gẹ́ bí O ti pese fun awọn ẹyẹ, ti wọn maa jade ni owurọ pẹlu ebi, ti wọn si maa pada ni irọlẹ ti wọn si ti yó.”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
61. Ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu alamọri wa yii ninu nnkan ti ko si nibẹ, wọn maa da a pada ni
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
62. Ẹ̀yin ẹrusin Mi, Emi ṣe abosi ni eewọ fun ara Mi, Mo si ṣe e ni eewọ laarin yin, ẹ ma ṣe abosi si ara yin - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
63. Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
64. Ẹru mi da ẹṣẹ kan, o wa sọ pé: Irẹ Ọlọhun, fi orí ẹṣẹ mi jin mi - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
65. “Dájúdájú àwọn onideede maa wa lori minbari latara imọlẹ ni ọdọ Ọlọhun, ni ọwọ ọtun Ajọkẹ-aye ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ọ̀tún si ni ọwọ Rẹ̀ méjèèjì - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
66. “Gbogbo ìjọ mi ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀ - 10 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
67. “Jibril kò yẹ̀ kò gbò ni ẹni tí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi nipa aládùúgbò, titi ti mo fi lérò pé yoo mu u jogún”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
68. “Dájúdájú ọfọ̀ ati àsokọ́ra ati oògùn ifẹran, ẹbọ ni” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
69. “Njẹ ẹ mọ ohun ti n jẹ ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn?”, wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ ju, o sọ pé: “Oun naa ni ki o maa sọ nipa ọmọ-ìyá rẹ ohun ti o korira” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
70. “Ìwọ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa fi ara ni wọn, ki O fi ara ni in, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn, ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú oun naa” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
71. “Dájúdájú àwọn èèyàn kan n wọ inu dúkìá Ọlọhun ni ọ̀nà tí kò tọ́, wọn maa wọ iná ni Ọjọ́ Àjíǹde” - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
72. Ẹ sọra fun aba dida; nitori pe aba dida jẹ eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
73. “Ko si ẹrú kan ti Ọlọhun fi ṣe alaṣẹ lori awọn kan, ki o wa kú ni ọjọ́ ti o maa kú ti o si n tan àwọn ti wọn wa ni abẹ rẹ jẹ, àfi ki Ọlọhun ṣe alujanna ni eewọ fun un”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
74. “Gbogbo dáadáa sàárà ni”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
75. “Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
76. “Alágbára kọ ni ẹni tí ó bá le dá èèyàn mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n alágbára gangan ni ẹni tí ó bá le kápá ẹ̀mí rẹ nígbà ìbínú” - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
77. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara wé àwọn ènìyàn kan jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
78. Ẹni ti o ba ṣe amọ̀nà lọ sibi oore, o maa ní irú ẹsan ẹni tí ó bá ṣe e
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
79. Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "Ki o wa orogun fun Ọlọhun ti o si jẹ pe Oun ni O ṣẹda rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
80. “Ẹ ma bu àwọn òkú; torí pé wọn lọ ba nǹkan ti wọn ti síwájú”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
81. “Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
82. “Ẹni tí ba n ja okùn ẹbí ko nii wọ alujanna”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
83. “Olófòfóó ko nii wọ alujanna”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
84. “Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, ti o si fẹ ki ẹmi oun gùn, ki o maa da ẹbí pọ” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
85. “Ẹni tí ó bá kó ìpalára ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìpalára ba oun naa, ẹni tí ó bá ko ìnira ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìnira ba oun naa”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
86. “Iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ, ki ẹ yaa maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
87. “Ẹni tí ó bá ki irun asunbaa, onítọ̀hún ti wa nínú ààbò Ọlọhun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
88. “Ẹni tí ó bá gba Ọlọhun gbọ ati Ọjọ́ Ìkẹyìn, ki o maa sọ dáadáa tabi ki o dakẹ - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
89. “Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn ko nii ṣàánú ẹni tí kii ba ṣàánú àwọn èèyàn”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
90. “Dájúdájú èèyàn ti Ọlọhun koriira jù ni alátakò ti o le julọ” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
91. Ọ̀rọ̀ ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ mẹrin ni: SUBHAANALLAH, ati ALHAMDULILLAAH, ati LAA ILAAHA ILLALLOOH, ati ALLAHU AKBAR, èyíkéyìí ti o ba wù ọ ni o le fi bẹ̀rẹ̀ nínú wọn”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
92. Wọn bi ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa nǹkan ti o maa mu awọn èèyàn wọ alujanna julọ, o sọ pe: “Ìpayà Ọlọhun ati iwa dáadáa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
93. Itiju wa ninu igbagbọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
94. “Adua naa ni ìjọsìn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
95. “Gbólóhùn meji kan ti wọn fúyẹ́ lori ahọ́n, ti wọn wúwo ninu òṣùwọ̀n, ti Ajọkẹ-aye nífẹ̀ẹ́ si méjèèjì - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
96. “Ko si nǹkan kan ti o ni apọnle ni ọdọ Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - ju adua lọ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
97. “Sàárà kii din dúkìá kù, Ọlọhun kii le ẹrú kún pẹ̀lú amojukuro àyàfi ni iyì, ẹnikan ko nii tẹrí ba fun Ọlọhun àyàfi ki Ọlọhun gbe e ga”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
98. “Ẹni ti o ba dáàbò bo iyì ọmọ-ìyá rẹ, Ọlọhun maa dáàbò bo ojú rẹ kuro nibi iná ni Ọjọ́ Àjíǹde”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
99. “Ẹni ti o ba sọ pe: SUBHAANALLOOHI WA BIHAMDIHII, ni ìgbà ọgọ́rùn-ún ni ojúmọ́, wọn maa pa àwọn ẹṣẹ rẹ rẹ kódà ki o da gẹgẹ bii ìfòfó agbami odò”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
100. “Ẹni tí ó bá sọ pé: LAA ILAAHA ILLALLOOH WAHDAHUU LAA SHARIIKA LAHUU, LAHUL MULKU WALAHUL HAMDU, WA UWA ALAA KULLI SHAY'HIN KỌDIIR, ni ẹẹmẹwaa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
101. “Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ́ oore fun, yoo fun un ni agbọye ninu ẹsin - 6 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
102. “Dájúdájú Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ẹrú ti o jẹ olupaya ọlọ́rọ̀ ti o pamọ́” - 6 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
103. Dajudaju ẹ maa ri Oluwa yin gẹgẹ bi ẹ ṣe n ri òṣùpá yìí, ẹ o nii ri inira nibi riri rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
104. Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii da lọ́fíńdà padà
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
105. “Mumini ti o pe jù ni igbagbọ ni ẹni tí ìwà rẹ dara ju, ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí o dara ju fun awọn obinrin wọn” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
106. “Ayé ìgbádùn ni, eyi ti o loore ju ninu ìgbádùn ayé ni obìnrin rere”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
107. “Dájúdájú ẹ̀lẹ̀ ko nii wa ninu nǹkan ayafi ki o ko ọ̀ṣọ́ ba a, wọn ko si nii yọ ọ kuro ninu nǹkan ayafi ki o ko àléébù ba a” - 14 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
108. “Dájúdájú Ọlọhun maa n yọnu si ẹrú ti o ba jẹun ti o wa dúpẹ́ lori rẹ, tabi ti o mu ti o wa dupẹ lórí rẹ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
109. “Dájúdájú pẹ̀lú iwa dáadáa, mumini maa de ipo aláàwẹ̀ ti n dide fun ìjọsìn ni oru”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
110. Dájúdájú ninu awọn ti wọn loore ju ninu yin ni àwọn tí ìwà wọn dára julọ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
111. “Ọlọhun sọ pe: Maa na owó irẹ ọmọ Anọbi Adam, Ọlọhun maa fi òmíràn rọ́pò”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
112. “Dájúdájú Ọlọhun maa n lọ́ alabosi lára, titi ti yoo fi mu u ti ko si nii jẹ ki ó bọ́
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
113. “Mi o fi fitina kan kan sílẹ̀ lẹyin mi ti o ni àwọn ọkùnrin lara ju àwọn obìnrin lọ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
114. “Ẹ maa ṣe idẹkun fun awọn èèyàn, ẹ ma ṣe fi ara ni wọn, ẹ maa fun awọn èèyàn ni ìró ìdùnnú, ẹ ma ṣe lé wọn sá”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
115. “Ẹ maa ka Kuraani yii ni ìgbà gbogbo, mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad n bẹ lọ́wọ́ Rẹ bura, o yara sá lọ ju ràkúnmí ninu okùn ti wọn fi dè é lọ” - 18 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
116. “Ẹni tí ó loore ju ninu yin ni ẹni tí ó kọ́ Kuraani ti o si tun kọ́ ẹlòmíràn” - 22 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
117. “Ẹni ti o ba sọkalẹ si ààyè kan, ti o wa sọ pé: AUUZU BIKALIMAATIL LAAHIT-TAMMAATI MIN SHARRI MAA KHỌLAK, nǹkan kan ko nii ni in lara titi ti yoo fi kuro ni aaye rẹ yẹn” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
118. Ṣe ki n gbe ọ dìde lori nnkan ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe mi dìde lórí ẹ? Ma fi ère kan kan silẹ àfi ki o pa a rẹ, ma si fi sàréè ti o ga kan kan silẹ afi ki o jẹ ki o bá ilẹ̀ dọ́gba - 6 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
119. “Ẹni kan kan ninu yin ko nii gbagbọ ni ododo titi ti yoo fi nífẹ̀ẹ́ mi ju baba rẹ, ati ọmọ rẹ, ati awọn èèyàn ni apapọ lọ” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
120. “Kii ṣe ara wa ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e, tabi ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun, tabi ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
121. “Ẹni ti o ba lọ ba yẹmiwo kan ti o wa bi i leere nipa nnkan kan, wọn ko nii gba irun rẹ fun ogoji ọjọ” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
122. “Ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ latara ìràwọ̀, onítọ̀hún ti gba ẹka kan ninu oògùn, bi o ba ṣe n lekun ninu imọ ìràwọ̀ naa ni kikọ oògùn rẹ naa ṣe maa lékún”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
123. ”Eyi ti o lẹtọọ julọ ninu awọn majẹmu lati mu ṣẹ ni nnkan ti ẹ fi sọ awọn abẹ di ẹtọ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
124. Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti o dara julọ ni iwa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
125. Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi wọn ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin gbogbo irun kọọkan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
126. “Ẹ ko gbọdọ sọ awọn ile yin di awọn iboji, dajudaju eṣu maa n sa kuro nibi ile ti wọn maa n ka Suratul Bakọra nibẹ” - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
127. “Ki n sọ pe: Subhaanallah, wal hamdulillah, wa laa ilaaha illallohu, wallohu akbar, jẹ nnkan ti mọ nifẹẹ sí ju nnkan ti oorun ran le lori lọ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
128. Ko sí ọjọ kankan ti iṣẹ oloore inu rẹ jẹ eyi ti Ọlọhun nifẹẹ si julọ ti o to awọn ọjọ yii» ìyẹn ni awọn ọjọ mẹwaa akọkọ Dhul Hijjah - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
129. Ẹni ti o ba gbe irun Asr ju silẹ, dajudaju iṣẹ rẹ ti bajẹ” - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
130. “Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
131. Ẹni ti o ba ka aayah meji ti o gbẹyin Sūratul Bakọra ni oru kan, wọn ti to fún un - 8 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
132. Ẹni ti o ba ka harafi kan ninu tira Ọlọhun, o maa fi gba ẹsan daada kan, ati pe ẹsan kan yio maa ni ilọpo mẹwaa iru rẹ - 8 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
133. “Tí ọmọniyan ba nawo lori awọn ara ile rẹ ti o n reti ẹsan rẹ lọdọ Ọlọhun, saara ni o jẹ fun un”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
134. “Igbagbọ jẹ ipin aadọrin ati nnkankan- tabi ọgọta ati nnkankan-, eyi ti o ni ọla julọ nibẹ ni gbolohun Laa ilaaha illallohu, eyi ti o kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro lọna
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
135. Ẹ̀gbà ọrùn kan ti wọn fi okùn ọfà tín-ín-rín ṣe ko gbọdọ ṣẹku ni ọrun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tabi ẹgba ọrun kan afi ki wọn ge e” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
136. “Ẹni ti o ba sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOHU, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ ti jẹ eewọ, ati pe ìṣirò rẹ wa lọ́wọ́ Ọlọhun”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
137. Dajudaju iwa Anabi Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni Kuraani
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
138. Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa - 18 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
139. Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ranti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ni gbogbo igba - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
140. Dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kọ nkan ti n jẹ al-Qaza‘ (ki èèyàn fá orí apakan ki o dá apakan sí)
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
141. Ọrọ yẹn ninu ododo ti alujannu n ji gbọ ni o wa, yoo waa gbe e si eti aayo rẹ gẹgẹ bi adiyẹ ṣe maa n gbe ọrọ fun adiyẹ miran, nigba naa ni wọn o waa ro irọ to le ni ọgọrun-un mọ ọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
142. A wa ni ọdọ ‘Umar, o wa sọ pe: «Wọn kọ fun wa kuro nibi ifipaṣe-nnkan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
143. Ko si ẹni kankan ti o n jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Allahu, ati pe Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni lododo lati inu ọkan rẹ, afi ki Ọlọhun ṣe ina leewọ fun un
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
144. Oluwa wa ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ṣẹku idamẹta igbẹyin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
145. Ẹ ma ṣe jokoo si ori awọn sàréè, ẹ ko si gbọdọ kirun si i lara
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
146. Awọn wọnyẹn ni ìjọ kan, ti ẹru rere ba ku ninu wọn tabi ọkùnrin rere, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
147. Wọn pa mi laṣẹ ki n fi ori kan'lẹ lori oríkèé meje
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
148. Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n sọ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: «Allāhummọ igfir li, warhamnī, wa ‘āfinī, wahdinī, warzuqnī - 6 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
149. Allahumo Anta-s- Salaam wa minka-s- Salaam, Tabaarakta Zal Jalaali wal Ikroom
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
150. Ki irun ni iduro, ti oo ba wa ni ikapa, yaa ki i ni ijokoo, ti oo ba tun wa ni ikapa, ki i ni ifẹgbẹlelẹ - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
151. Njẹ o maa n gbọ ipe irun?» O sọ pe: Bẹẹ ni, o sọ pe: «Ki o ya dahun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
152. Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ wa ni khutubal haajah - 4 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
153. “Ko si igbeyawo kan afi pẹlu alaṣẹ obinrin”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
154. Irẹ ọmọdekunrin yii, darukọ Ọlọhun, ki o si jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ki o si tun jẹ ninu nkan ti o sunmọ ọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
155. “Ti ẹnikẹni ninu yẹn ba fẹ jẹun ki o yaa jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ, ti o ba si fẹ mu ki o yaa mu pẹlu ọwọ ọtun rẹ, dajudaju Shaitan maa n jẹun pẹlu ọwọ osi rẹ, o si maa n mu pẹlu ọwọ osi rẹ” - 2 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
156. “Ẹni ti o ba jade kuro ninu itẹle, ti o wa fi janmọọn sílẹ̀, ti o wa ku, o ku ni iku ti asiko aimọkan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
157. Ẹni ti o ba wa ba yin nigba ti ọrọ yin papọ lori arakunrin kan, ti o wa n gbero láti ya yin, tabi lati pin akojọpọ yin, ki ẹ yaa pa a
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
158. “Ẹni ti o ba pa ẹni a gba adehun lọwọ rẹ ko nii gbọ́ oorun alujanna, ati pe dajudaju oorun rẹ wọn maa n gbọ́ ọ lati ijinna ogoji ọdun” - 6 ملاحظة
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
159. Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣẹ́ ibi lé ẹni ti n san abẹtẹlẹ ati ẹni ti n gba a nibi idajọ (igbẹjọ)
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
160. Ẹni ti o ba kọ oju ija si wa pẹlu ohun ìjà, ko kii ṣe ara wa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu