3. Dajudaju wọn n jẹ awọn mejeeji niya lọwọ, wọn o si jẹ wọn niya nitori alamọri nla kan (ni iwoyesi awọn eeyan), ẹ o wa ri ọkan ninu awọn mejeeji o jẹ ẹni ti kii mọra kuro nibi itọ, amọ ẹnìkejì o jẹ ẹni ti maa n gbé ọrọ ofofo kaakiri - 4 ملاحظة
6. dajudaju ẹjẹ iṣan niyẹn, ṣugbọn maa fi irun silẹ ni odiwọn awọn ọjọ ti o fi maa n ri ẹjẹ nkan oṣu, lẹyin naa ki o wa wẹ ki o si kirun
7. Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe aluwala ki o ya fi omi si imu rẹ lẹyin naa ki o fin in síta, ẹni ti o ba fẹ fi okuta mọra ki o ya ṣe e ni witiri
8. Ti ọkùnrin ba wọ inu ile rẹ, ti o wa ranti Ọlọhun nigba ìwọlé rẹ ati nibi oúnjẹ rẹ, Shaitan maa sọ pé: Ko si ibusun fun yin ko si si oúnjẹ alẹ naa - 2 ملاحظة
9. Dajudaju aye jẹ nnkan ti o dun ti o si tutu, ati pe dajudaju Ọlọhun n fi yin ṣe arole nibẹ, ti yoo maa wo nnkan ti ẹ ń ṣe, ẹ bẹru aye ki ẹ si bẹru obinrin - 2 ملاحظة
11. Ṣe ẹnikọọkan yin o maa bẹru - tabi: Ẹnikọọkan yin o bẹru - nigba ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju imaamu, ki Ọlọhun o sọ ori rẹ di ori Kẹtẹkẹtẹ, tabi ki o sọ aworan di aworan Kẹtẹkẹtẹ
12. Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ mi ni ataya, ti atẹlẹwọ mi wa laaarin atẹlẹwọ rẹ mejeeji, gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ mi ni Surah ninu Kuraani
13. Irẹ Ọlọhun dajudaju emi wa iṣọra pẹlu Rẹ kuro nibi iya saare, ati nibi iya ina, ati nibi fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi fitina al-Masiihu ad-Dajjāl - 2 ملاحظة
14. Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wọ aaye ẹgbin yio sọ pe: «Allaahummọ inni a‘uudhu biKa minal khubuthi wal khabaaithi
15. Imọtaraẹni-nikan maa wa ati awọn àlámọ̀rí kan ti ẹ maa takò wọn" wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni nnkan ti o maa pa wa láṣẹ? O sọ pe: "Ẹ maa pe ẹtọ ti o jẹ dandan fun yin, ẹ si maa beere lọwọ Ọlọhun nnkan ti o jẹ ti yin
16. Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, yio fọ ọwọ rẹ mejeeji, yio si tun ṣe aluwala rẹ ti maa n ṣe fun irun, lẹyin naa yio wẹ
17. Apejuwe ẹni ti o duro nibi aala Ọlọhun ati ẹni ti o ko sinu rẹ, da gẹgẹ bi apejuwe awọn ijọ kan ti wọn mu aje lori ọkọ oju-omi, ni apakan wọn wa bọ si oke rẹ ti apakan wọn si wa ni isalẹ rẹ - 8 ملاحظة
18. Mo jẹ ọkùnrin kan ti o maa n da atọ ireke lọpọlọpọ, mo maa n tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nitori ipo ọmọbinrin rẹ, mo wa pa Miqdad ọmọ Al-Aswad láṣẹ o si beere lọwọ rẹ, o sọ pe: "O maa fọ nnkan ọmọkunrin rẹ yoo si ṣe aluwala
19. Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ
20. Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa gbagbọ, ati pe e ko lee gbagbọ titi ti ẹ fi máa nífẹ̀ẹ́ ara yin, ẹ wa jẹ ki n juwe yin si nkankan ti o jẹ pe ti ẹ ba ṣe e ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yin? Ẹ maa tan salamọ ka laarin ara yin - 2 ملاحظة
21. Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nifẹẹ si julọ? O sọ pe: "Irun kiki ni asiko rẹ", o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Lẹyin naa ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji" o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Jija ogun si oju ọna Ọlọhun - 2 ملاحظة
22. Dajudaju arakunrin kan jẹun lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu ọwọ osi rẹ, o sọ pe: "Jẹun pẹlu ọwọ ọtun rẹ", o sọ pe: Mi ko ni ikapa, o sọ pe: "O ò sì nii ní ikapa
23. Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn
24. Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni,- lẹẹmẹta-", ko si ninu wa afi, ṣùgbọ́n Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- n mu u lọ pẹlu igbarale Ọlọhun
25. ni a wa sọ pe: Iwọ ni olowo wa, ni o wa sọ pe: "Allāhu ni Olowo", a sọ pe: ati ọlọlajulọ inu wa, ati ọlọrọ julọ inu wa, ni o wa sọ pe: «Ẹ maa sọ awọn ọrọ yin, tabi apakan awọn ọrọ yin, ẹ ma jẹ ki esu o lo yin (ki o gbe yin kọja aala)
26. Ẹyin eniyan, ẹ ṣọ́ra kuro nibi aṣeju nibi ẹsin, dajudaju nnkan ti o pa àwọn ti wọn ṣíwájú yin run ni aṣeju nibi ẹsin
27. Irẹ ọmọ-iya baba mi, sọ pe: Laa illaha illā Allāhu, gbolohun kan ni ti maa fi jẹrii gbe ọ ni ọdọ Allāhu
28. Ko si akoran, ko si si ifi ẹyẹ fura mọ daadaa tabi aburu, ati pe mo fẹ́ràn fah'lu, o sọ pe wọn sọ pe: Kí ni fah'lu? O sọ pe: "Ọrọ ti o daa
29. Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dajudaju o sọ nipa awọn Ansar pe: "Ẹnikan ko nii nífẹ̀ẹ́ wọn afi olugbagbọ, ẹnikan ko si nii korira wọn afi sobẹ-ṣelu, ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ wọn, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ
31. O ti to fun ẹ ki o fi ọwọ rẹ mejeeji ṣe bayii» lẹyin naa ni o fi ọwọ rẹ mejeeji lu ilẹ ni ẹẹkan, lẹyin naa ni o fi osi pa ọtun, ati ẹyin ọwọ rẹ mejeeji ati oju rẹ
32. Mo maa n wẹ emi ati Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu igba kan naa ti awa mejeeji si jẹ ẹni ti o ni janaba lara, o maa n pa mi láṣẹ, ti maa si ro iro, ti o si maa n sunmọ mi ti mo si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu,
33. Mo ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori jijẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ati gbigbe irun duro, ati yiyọ saka, ati gbigbọ ati itẹle, ati ṣíṣe iṣiti fun gbogbo Musulumi
34. Ẹ bẹru Ọlọhun Oluwa yin, ẹ ki irun wakati marun-un yin, ẹ gba awẹ oṣu yin, ẹ yọ saka awọn dukia yin, ẹ tẹle adari àlámọ̀rí yin ẹ maa wọ alujanna Olúwa yín
35. Tọ mi sọ́nà lori iṣẹ kan ti mo ba ṣe e maa wọ alujanna, o sọ pe: "Maa jọsin fun Ọlọhun ki o si ma da nnkan kan pọ mọ Ọn, ki o maa gbe irun ti a ṣe ni dandan duro, ki o maa yọ saka ti a ṣe ni ọran-anyan, ki o maa gba awẹ Ramadan - 2 ملاحظة
37. lori ki ni a maa ṣadehun fun ẹ? O sọ pe: "Lori pe ẹ ma maa jọsin fun Ọlọhun ẹ ko si gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn, ati awọn irun maraarun-un, ẹ si gbọdọ maa tẹle- o wa sọ ọrọ kan ti o pamọ ni jẹjẹ- ẹ ko si gbọdọ beere nnkan kan lọwọ awọn eniyan
38. Wọn pa mi láṣẹ lati ba awọn eniyan ja titi wọn maa fi jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti wọn si n gbe irun duro, ti wọn si n yọ saka
39. Ẹni ti o n gun nkan ni o maa salamọ si ẹni ti o n rin, ẹni ti o n rin ni o máa salamọ si ẹni ti o jokoo, awọn ti onka wọn kere ni wọ́n maa salamọ si awọn ti onka wọn pọ
40. “Irun ọkunrin kan pẹ̀lú janmọọn ju irun rẹ nile lọ ati Irun rẹ ni ọja lọ pẹlu ipò ogún lé ní nǹkan kan
41. Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si
42. Ẹ sọ fun mi ti akeremọdo kan ba wa ni ẹnu ọ̀nà ẹni kọọkan ninu yin ti o n wẹ nibẹ ni ojoojumọ lẹẹmarun-un, njẹ ìyẹn le ṣẹ nǹkan kan kù nínú ìdọ̀tí rẹ bi? - 2 ملاحظة
43. Apejuwe awọn Mumuni nibi nini ifẹ ara wọn ati kikẹ ara wọn ati nini aanu ara wọn da gẹgẹ bi apejuwe odidi ara, nigba ti orike kan ba n ke irora gbogbo ara yoku ni yio para pọ pẹlu rẹ nibi aisun ati igbona - 8 ملاحظة
44. Ẹ pa awọn ọmọ yin láṣẹ pẹlu irun ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun meje, ẹ na wọn lori rẹ ti wọn ba ti wa ni ọmọ ọdun mẹwaa, ẹ ṣe opinya laaarin wọn nibi awọn ibusun - 2 ملاحظة
45. Ko si nkankan ti o wuwo julọ ninu oṣuwọn Mumuni ni ọjọ igbedide ti o to iwa daadaa, ati pe dajudaju Ọlọhun a maa korira onibajẹ onisọkusọ - 2 ملاحظة
46. Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jade si wa, a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a ti kọ bi a ṣe maa salamọ si ẹ, bawo ni a ṣe maa ṣe asalatu fun ẹ? - 2 ملاحظة
48. Mumini alagbara ni oore o si tun jẹ ẹni ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ju Mumini ọlẹ lọ, ọkọọkan wọn si ni oore wa lara rẹ,
49. Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀yìn, ki O si daabo bo wa nibi iya ina”.))
51. Ẹ paya abosi, nitori pe abosi jẹ awọn okunkun ni ọjọ igbedide, ẹ paya ahun, nitori pe ahun lo pa awọn ti wọn ṣáájú yin run, - 2 ملاحظة
52. Dajudaju arakunrin kan bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Isilaamu wo lo fi n loore julọ? O sọ pe: «Ki o maa funni ni ounjẹ, ki o si tun maa salamọ si ẹni ti o mọ ati ẹni ti o ko mọ
55. Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, o si ba a sọrọ nipa ọrọ kan, o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, ti iwọ anabi si fẹ. ” Nígbà náà ni Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, wí pé: “ṣé iwọ o fi mí ṣe bakannaa pẹlu Ọlọ́run ni? Sọ pé: Ohunkóhun tí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo bá fẹ́”
56. Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun
57. {Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan
58. Sọ pe: Laa ilaaha illallohu wahdaHu laa shariika laHu, Allahu Akbar kabeeran, wal amdulillah katheeran, Subhaanallah Robbil 'aalameen, laa haola wa laa quwwata illa billahil Azeezil Hakeem - 6 ملاحظة
59. Ko si ninu ọmọniyan to jẹ musulumi ti irun ọran-anyan kan wa ba a, ti o wa ṣe aluwala rẹ daadaa ati ipaya rẹ ati rukuu rẹ, afi ki o jẹ ipa ẹṣẹ rẹ fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ, niwọn igba ti ko ba mu ẹṣẹ nla wa, gbogbo igba si ni ìyẹn maa ri bẹ́ẹ̀
60. “Àpèjúwe Mumini ti n ka Kuraani da gẹgẹ bii èso utrujjah, ti oorun rẹ daa, ti itọwo rẹ naa si daa, àpèjúwe mumini ti kii ka Kuraani da gẹgẹ bii èso dabinu, ti ko ni oorun, ti itọwo rẹ si dùn - 8 ملاحظة
61. Awọn gbolohun ẹyin irun kan n bẹ ti o ṣe pe ẹni ti o ba sọ wọn - tabi ti o ṣe wọn - ni ẹyin gbogbo irun ọranyan, ko ni mofo, subhānallāh ọgbọn ati mẹta, ati alhamduliLlāhi ọgbọn ati mẹta, ati Allāhu akbar ọgbọn ati mẹẹrin
62. Ẹni ti o ba sọ nigba ti o n gbọ oluperun pe ash-hadu an laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharika laHu, wa anna muhammadan ‘abduHu wa rosuuluhu, rodiitu bil Laahi robban wa bi muhammadin rosuulan wa bil Isilaami diina, wọn a fi ori ẹṣẹ rẹ jin in
64. Ẹni ti o ba mu aayo mi ni ọta, Mo ti kede ogun pẹlu rẹ, ati pe ẹru Mi o nii sunmọ Mi pẹlu nkankan ti Mo nífẹ̀ẹ́ si ju nkan ti Mo ṣe ni ọranyan fun un lọ - 2 ملاحظة
66. Dajudaju arakunrin kan ṣe aluwala ni o wa fi aaye eekanna silẹ nibi ẹsẹ rẹ, ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ri i ti o si sọ pe: «Pada ki o si lọ ṣe aluwala rẹ daadaa» ni o ba pada, lẹyin naa ni o kirun
67. Awọn iran eniyan meji kan wa ninu ara ina ni wọn, mi ko ri wọn, ijọ kan ni ti awọn ọrẹ n bẹ pẹlu wọn ti wọn da gẹgẹ bi awọn iru maluu ti wọn maa n fi i na awọn eniyan, ati awọn obinrin kan wọn maa wọ aṣọ wọn si maa wa ni ihoho, ti wọn maa n mu ẹlòmíràn yẹ gẹrẹ, ti awọn gan ti yẹ̀ gẹ̀rẹ̀
72. Iwẹ ọjọ Jimoh jẹ dandan lori gbogbo ẹni ti o ti balaga, ki o si fi pako run awọn eyin rẹ, ki o si lo lọ́fíńdà ti o ba ri - 4 ملاحظة
73. Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi
75. Ẹni ti o ba ṣe afọmọ fun Ọlọhun (Subhānallāh) ni ẹyin gbogbo irun kọọkan ni igba mẹtalelọgbọn, ti o si tun dupẹ fun Ọlọhun (AlhamduliLlāhi) ni igba mẹtalelọgbọn, ti o tun wa gbe titobi fun Ọlọhun (Allāhu akbar) ni igba mẹtalelọgbọn, ìyẹn jẹ ọgọrun din ẹyọkan, ti o wa sọ ni ipari ọgọ́rùn-ún pe: Lā ilaha illā Allāhu wahdahu lā sharīka laHu, laHul mulku, wa laHul hamdu, wa Huwa alā kulli shayhin qadīr, wọn o fi ori gbogbo ẹṣẹ rẹ jin in kódà ki o to deede fóòmù ori omi okun - 2 ملاحظة
76. Ẹni ti o ba ka āyatul kursiyyu ni ẹyin irun ọranyan kọọkan, ko si nkan ti yio di i lọwọ wiwọ al-jannah ayaafi ki o ku
77. O daju pe ẹsin yii a de gbogbo ibi tí oru ati ọsan de, ati pe Ọlọhun o nii fi ile kankan silẹ bóyá ilé alámọ̀ ni abi ilé onírun ayafi ki O mu ẹsin yii wọ ibẹ
78. Ti ẹnikẹni ninu yin ba ṣe iyemeji nibi irun rẹ, ti ko si mọ iye ti o ki boya mẹta ni tabi mẹrin, ki o yaa ju iyemeji naa nù, ki o mọ irun rẹ lori nnkan ti o da a loju, lẹyin naa, o maa forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹẹmeji ṣíwájú ki o to salamọ
79. Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira ọti ni, ati pe gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira eewọ ni, ati pe ẹni ti o ba mu ọti ni aye ti o wa ku ni ẹni ti o kúndùn rẹ ti ko tuuba, ko nii mu un ni ọjọ ikẹyin - 6 ملاحظة