عن المِقدام بن معدي كرب رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«إِذَا أَحَبَّ الرَّجُلُ أَخَاهُ فَلْيُخْبِرْهُ أَنَّهُ يُحِبُّهُ».
[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي والنسائي في السنن الكبرى وأحمد] - [سنن أبي داود: 5124]
المزيــد ...
Lati ọdọ Al-Miqdam ọmọ Maadi Karib, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe:
“Bí ọkùnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀, kí ó sọ fún un pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀”.
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy gba a wa ninu As-Sunanul Kubrọ, ati Ahmad] - [Sunanu ti Abu Daud - 5124]
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, n ṣe alaye ọkan lara awọn okunfa ti o lè fun ajọṣepọ ati ifẹ lagbara laarin awọn onigbagbọ ododo, òun naa ni pe ti ẹnikẹni ba nífẹ̀ẹ́ arakunrin rẹ̀, ki o sọ fun un pe oun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.