عن معاوية رضي الله عنه قال: سمعت النبي صلى الله عليه وسلم يقول:
«مَنْ يُرِدِ اللهُ بِهِ خَيْرًا يُفَقِّهْهُ فِي الدِّينِ، وَإِنَّمَا أَنَا قَاسِمٌ، وَاللهُ يُعْطِي، وَلَنْ تَزَالَ هَذِهِ الْأُمَّةُ قَائِمَةً عَلَى أَمْرِ اللهِ، لَا يَضُرُّهُمْ مَنْ خَالَفَهُمْ، حَتَّى يَأْتِيَ أَمْرُ اللهِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 71]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Muaawiyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
“Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ́ oore fun, yoo fun un ni agbọye ninu ẹsin, olùpín ni mi, Ọlọhun ni n fúnni, ìjọ yii ko nii dẹkun lati maa duro lori àṣẹ Ọlọhun, ti ẹni tí ó bá yapa wọn ko si nii ko ìpalára ba wọn, titi ti àṣẹ Ọlọhun yoo fi dé”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 71]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fun, O maa fun un ni agbọye ninu ẹsin Rẹ, oun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si ni olupin, o maa n pin ohun ti Ọlọhun ba fun un ninu arisiki ati imọ ati awọn nǹkan mìíràn, ati pe ẹni ti n fúnni gan ni Ọlọhun, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n o kii ṣe olohun jẹ okùnfà ti ko lee ṣe anfaani kankan ayafi pẹ̀lú iyọnda Ọlọhun, ìjọ yii ko nii dẹkun lati maa duro lori àṣẹ Ọlọhun, ti ẹni tí ó bá yapa wọn ko si nii ko ìpalára ba wọn, titi ti ayé fi maa parẹ”