+ -

عن عائشة رضي الله عنها قالت: سمعتُ من رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول في بيتي هذا:
«اللَّهُمَّ مَنْ وَلِيَ مِنْ أَمْرِ أُمَّتِي شَيْئًا فَشَقَّ عَلَيْهِمْ فَاشْقُقْ عَلَيْهِ، وَمَنْ وَلِيَ مِنْ أَمْرِ أُمَّتِي شَيْئًا فَرَفَقَ بِهِمْ فَارْفُقْ بِهِ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1828]
المزيــد ...

Lati ọdọ Aisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ lẹ́nu ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ ninu ilé mi yii pe:
“Ìwọ Ọlọhun, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa fi ara ni wọn, ki O fi ara ni in, ẹnikẹni ti o ba jẹ alaṣẹ lori nǹkan kan ninu ijọ mi, ti o wa ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn, ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú oun naa”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1828]

Àlàyé

Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣẹ èpè lé gbogbo ẹni tí ó bá jẹ alaṣẹ lori àlámọ̀rí kan fun awọn Mùsùlùmí, bóyá o kéré ni tabi o tóbi, bóyá ti gbogbogboo ni tabi fun apá ibikan sọ́, tí o wa fi ara ni wọn ti ko ṣàánú wọn, pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa san an lẹsan latara irú iṣẹ rẹ pẹlu pe ki o fi ara ni oun náà.
Ẹni tí ó bá wa ṣàánú wọn ti o si ṣe àlámọ̀rí wọn ni irọrun, pe ki Ọlọhun ṣàánú tiẹ̀ naa ki O si ṣe àlámọ̀rí rẹ ni irọrun.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. O di dandan fún ẹni tí o ba jẹ alaṣẹ lori nnkan kan ninu àlámọ̀rí àwọn Musulumi ki o ṣe pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú wọn bi o ba ṣe kápá mọ.
  2. Ẹsan maa wa latara iran iṣẹ.
  3. Òṣùwọ̀n ohun ti a maa kà kún ninu ìwà pẹ̀lẹ́ tabi ilekoko ni ohun ti ko ba ti tako Kuraani ati Sunna.