عن أبي هريرة رضي الله عنه:
أَنَّ رَجُلًا قَالَ لِلنَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: أَوْصِنِي، قَالَ: «لَا تَغْضَبْ» فَرَدَّدَ مِرَارًا قَالَ: «لَا تَغْضَبْ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 6116]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Arákùnrin kan sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi, o sọ pé: “Ma ṣe maa binu”, o wa pààrà rẹ ni ọpọlọpọ ìgbà, o tun sọ pé: “Ma ṣe maa bínú”.
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6116]
Ọ̀kan ninu awọn saabe- ki iyọnu Ọlọhun maa ba wọn- wá láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ki o tọka òun si nǹkan kan tí o maa ṣe e ni anfaani, o wa pa a láṣẹ ki o ma maa bínú, itumọ ìyẹn ni pe ki o jìnnà si awọn okùnfà ti o le mu u binu, ki o si ko ara rẹ ni ìjánu ti ìbínú bá ṣẹlẹ̀, ki o ma tẹ síwájú nibi ibinu rẹ pẹlu pípa, tàbí lílù, tabi èébú, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Arákùnrin naa paara wíwá àsọtẹ́lẹ̀ naa ni ọpọlọpọ ìgbà, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko sọ fun un nibi àsọtẹ́lẹ̀ naa ju pe “ma ṣe maa binu”.