عن أبي سعيد الخُدْريِّ رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«مَنْ رَأَى مِنْكُمْ مُنْكَرًا فَلْيُغَيِّرْهُ بِيَدِهِ، فَإِنْ لَمْ يَسْتَطِعْ فَبِلِسَانِهِ، فَإِنْ لَمْ يَسْتَطِعْ فَبِقَلْبِهِ، وَذَلِكَ أَضْعَفُ الْإِيمَانِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 49]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Sa’eed Al-Khudri- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n sọ pe:
"Ẹni ti o ba ri ibajẹ kan ninu yin, ki o yi i pada pẹlu ọwọ rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ, ati pe ìyẹn ni o lẹ julọ ninu igbagbọ".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 49]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n pàṣẹ yiyi ibajẹ- oun ni gbogbo nnkan ti Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ kọ kuro nibẹ- pada, ni ibamu bi ikapa ba ṣe mọ, nitori naa ti o ba ri ibajẹ kan, yiyi i pada pẹlu ọwọ jẹ dandan fun un ti ikapa ba n bẹ fun un, ṣugbọn ti o ba kagara kuro nibi ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ pẹlu pe ki o kọ fun ẹni ti o ba ṣe e ki o si ṣàlàyé inira ti o n bẹ nibẹ fun un, ki o si tọ ọ sọ́nà lọ si ibi daadaa dipo aburu yii, Tí o ba kagara kuro nibi ipo yii, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ pẹ̀lú ki o korira ibajẹ yii, yoo si ni ipinnu pe ti oun ba ni ikapa lori yiyi i pada ni ko ba ṣe bẹẹ, Yiyi pada pẹlu ọkan jẹ eyi ti o lẹ julọ ninu awọn ipo igbagbọ nibi yiyi ibajẹ pada.