+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم كان يقول:
«الصَّلَوَاتُ الْخَمْسُ، وَالْجُمُعَةُ إِلَى الْجُمُعَةِ، وَرَمَضَانُ إِلَى رَمَضَانَ، مُكَفِّرَاتٌ مَا بَيْنَهُنَّ إِذَا اجْتَنَبَ الْكَبَائِرَ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 233]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Huraira - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - máa n sọ pé:
"Awọn ìrun wakati maraarun, Irun Jimọ sí Jimọ, Ramadan sí Ramadan, ó máa n pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí n bẹ laarin wọn rẹ́ ni, tí eniyan bá ti jìnnà sí awọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá".

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 233]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fun wa pé dajudaju awọn ìrun ọ̀ranyàn wakati maraarun lojoojumọ, irun Jimọ ni gbogbo ọsẹ, gbigba aawẹ oṣu Ramadan ni gbogbo ọdun, ó máa n pa awọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké tí eniyan bá dá laarin wọn rẹ́ ni, pẹlu majẹmu pé kí eniyan jìnnà si awọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá, àmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá, gẹgẹ bii ṣìná àti ọtí mímu, wọn kò nii pa a rẹ́ àyàfi kí eniyan túúbá kúrò níbẹ̀ kó sì ronúpìwàdà.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Awọn ẹ̀ṣẹ̀ yẹn, kéékèèké n bẹ ninu wọn, ńlánlá naa sì n bẹ ninu wọn.
  2. Majẹmu pípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kéékèèké rẹ́ ni jíjìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlánlá.
  3. Awọn ẹ̀ṣẹ̀ nlanla ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ti ijiya wà lori rẹ̀ ni aye, tabi ileri ijiya tabi ibinu Ọlọhun wà lori rẹ̀ ní ọ̀run, tàbí ìdẹ́rùbani wà lori rẹ̀, tabi ibidandan Ọlọhun wà lori ẹnití ó ṣe e, gẹgẹ bii ṣìná àti ọtí mímu.