عن المقدام بن معدِيْكَرِب رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«أَلَا هَلْ عَسَى رَجُلٌ يَبْلُغُهُ الْحَدِيثُ عَنِّي وَهُوَ مُتَّكِئٌ عَلَى أَرِيكَتِهِ فَيَقُولُ: بَيْنَنَا وَبَيْنَكُمْ كِتَابُ اللهِ، فَمَا وَجَدْنَا فِيهِ حَلَالًا اسْتَحْلَلْنَاهُ، وَمَا وَجَدْنَا فِيهِ حَرَامًا حَرَّمْنَاهُ، وَإِنَّ مَا حَرَّمَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَمَا حَرَّمَ اللهُ».
[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي وابن ماجه] - [سنن الترمذي: 2664]
المزيــد ...
Lati ọdọ Al-Miqdam Bin Ma’dikarib- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
"Ẹ tẹti ẹ gbọ, o ṣee ṣe ki arakunrin kan, ki hadisi nipa mi de etigbọọ rẹ ti o si rọgbọku ni ori ibusun rẹ, ki o wa maa sọ pe: Iwe Ọlọhun n bẹ laaarin wa ati yin, nǹkan ti a ba ri nibẹ ni ẹtọ a maa ṣe e ni ẹtọ, nnkan ti a ba si ri nibẹ ni eewọ a maa ṣe e ni eewọ. Ati pe dajudaju nnkan ti Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ṣe ni eewọ da gẹgẹ bii nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ".
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ni wọn gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2664]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe asiko kan ti sunmọ ti iran kan ninu awọn eniyan o jẹ ẹni ti o jokoo nibẹ, ọkan ninu wọn maa rọgbọku ni ori ibusun rẹ, ti hadisi lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa de eti igbọ rẹ, yoo waa maa sọ pe: Nnkan ti o maa ṣe ìyàtọ̀ laaarin wa ati laaarin yin nibi awọn alamọri ni Kuraani Alapọn-ọnle, o si ti to wa, nnkan ti a ba ba nibẹ ninu nnkan ẹtọ a maa ṣiṣẹ pẹlu rẹ, nnkan ti a ba si ba nibẹ ninu nnkan eewọ a maa jina si i. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe gbogbo nnkan ti o ṣe ni eewọ tabi kọ kuro nibẹ ninu sunnah rẹ, ninu idajọ o da gẹgẹ bii nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ ninu iwe Rẹ; nitori pe oun ni o n jiṣẹ Oluwa rẹ.