+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«لَيْسَ الشَّدِيدُ بِالصُّرَعَةِ، إِنَّمَا الشَّدِيدُ الَّذِي يَمْلِكُ نَفْسَهُ عِنْدَ الْغَضَبِ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6114]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Alágbára kọ ni ẹni tí ó bá le dá èèyàn mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n alágbára gangan ni ẹni tí ó bá le kápá ẹ̀mí rẹ nígbà ìbínú”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6114]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe agbára gidi kii ṣe agbára ti ara, tabi ẹni ti o ba maa dá alágbára mìíràn mọ́lẹ̀. Alágbára gangan ni ẹni tí o ba ja ẹ̀mí rẹ lógun tí ó sì borí rẹ nígbà tí ìbínú rẹ bá n le; torí pé eyi n tọka si ikapa rẹ lori ẹmi ara rẹ ati ibori èṣù.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti n bẹ fun sùúrù ati ìdarí ẹ̀mí nígbà ìbínú, ati pe o wa ninu awọn iṣẹ rere ti Isilaamu ṣe wa ni ojúkòkòrò si.
  2. Jija ẹ̀mí ni ogun nígbà ìbínú le koko ju jija ọ̀tá ni ogun lọ.
  3. Isilaamu yi agbọye agbára ni asiko aimọkan padà si awọn iwa alapọn-ọnle, èèyàn ti o ni agbara ju ni ẹni tí ó ni ikapa ìjánu ẹ̀mí ara rẹ.
  4. Jijina si ìbínú; tori ìnira ti o maa n fa fun ènìyàn kọ̀ọ̀kan ati àwùjọ.