عن أبي ذر رضي الله عنه قال: قال لي النبي صلى الله عليه وسلم:
«لَا تَحْقِرَنَّ مِنَ الْمَعْرُوفِ شَيْئًا، وَلَوْ أَنْ تَلْقَى أَخَاكَ بِوَجْهٍ طَلْقٍ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2626]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Dharr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun mi pe:
“Ma ṣe fi oju kere nǹkan kan nínú dáadáa, koda ki o pàdé ọmọ-iya rẹ ki o si tújú ka si i”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2626]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe wa ni ojúkòkòrò lori ṣíṣe dáadáa, ki èèyàn si ma fi oju kéré rẹ kódà ki o kéré, ninu ìyẹn ni tituju ka pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ nígbà tí a ba pade. O tọ́ fun Mùsùlùmí ki o ṣe ojúkòkòrò rẹ; tori ifi ara ro ọmọ-ìyá ti o jẹ Mùsùlùmí wa ninu ẹ, ati mimu ìdùnnú wọ inu rẹ̀.