عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«كان رجلٌ يُدَايِنُ الناسَ، فكان يقول لفتاه: إذا أتيتَ مُعسِرًا فتجاوز عنه، لعل اللهَ يَتجاوزُ عنا، فلقي اللهَ فتجاوز عنه».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 1562]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
"Ọkùnrin kan wà tó máa ń yá àwọn eniyan ní owo, ó sì máa ń sọ fún ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ pé: Ti o bá de ọdọ alaini, ki o ṣamojukuro fun un, bóyá Ọlọ́hun yoo ṣamojukuro fún awa naa, ni ọkunrin yii bá pàdé Ọlọ́hun, Ọlọ́hun sì ṣamojukuro fun un".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 1562]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ nipa ọkunrin kan tí ó máa ń yá awọn eniyan ní owo gbese, tabi kí ó ta ọjà àwìn fún wọn, ó sì jẹ́ ẹniti o máa ń sọ fún ọmọ-ọdọ rẹ̀ tí o maa n lọ gba gbèsè tí awọn ènìyàn jẹ ẹ pé: Ti o bá dé ọdọ onigbese ti kò ní owo lati san gbese tó jẹ nitori ailagbara rẹ̀ "ṣamojukuro fun un"; bóyá ki o fun un ni akoko si, kí o sì ma sin in lagidi, tabi ki o gba ohun ti o wa ni ọwọ rẹ̀ naa, koda ki owo naa mai tii pe, o ṣe eleyii nitori pé ó ń fẹ́, ó sì n rankan pé kí Ọlọhun ṣamojukuro fun oun naa, ki O sì darijin oun, Nígbà ti ọkunrin yii kú, Ọlọ́hun dárí jìn in, Ó sì ṣamojukuro fun un nibi àwọn àṣìṣe rẹ̀.