+ -

عن جابر رضي الله عنه:
أَنَّ رَجُلًا سَأَلَ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَقَالَ: أَرَأَيْتَ إِذَا صَلَّيْتُ الصَّلَوَاتِ الْمَكْتُوبَاتِ، وَصُمْتُ رَمَضَانَ، وَأَحْلَلْتُ الْحَلَالَ، وَحَرَّمْتُ الْحَرَامَ، وَلَمْ أَزِدْ عَلَى ذَلِكَ شَيْئًا، أَأَدْخُلُ الْجَنَّةَ؟ قَالَ: «نَعَمْ»، قَالَ: وَاللهِ لَا أَزِيدُ عَلَى ذَلِكَ شَيْئًا.

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 15]
المزيــد ...

Lati ọdọ Jaabir- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Dajudaju arakunrin kan beere lọwọ Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe: Fun mi ni iro nipa ti mo ba ki awọn irun ọran-anyan, ti mo gba awẹ Ramadan, ti mo ṣe ẹtọ ni ẹtọ, ti mo ṣe eewọ ni eewọ, ti mi ko le nnkan kan kun lori ìyẹn, njẹ maa wọ alujanna? O sọ pe: “Bẹẹni”, o sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura pe mi ko nii le nnkan kan kun lori ìyẹn.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 15]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba ki awọn irun ọran-anyan maraarun-un ti ko le nnkankan kun ninu awọn nafila, ti o si gba awẹ Ramadan ti ko gba awọn aṣegbọrẹ, ti o ni adisọkan jijẹ ẹtọ nnkan ẹtọ ti o si ṣe é, ti o ni adisọkan jijẹ eewọ nnkan eewọ ti o si jina si i, dajudaju yoo wọ alujanna.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ojúkòkòrò Musulumi lori ṣíṣe awọn ọran-anyan ati gbigbe awọn eewọ ju silẹ, ati pe ki afojusun rẹ jẹ wiwọ alujanna.
  2. Ṣíṣe pataki ṣíṣe nnkan ẹtọ ati ini adisọkan jijẹ ẹtọ rẹ, ati ṣíṣe nnkan eewọ ni eewọ ati ini adisọkan jijẹ eewọ rẹ.
  3. Ṣíṣe awọn nnkan ti wọn jẹ dandan ati gbigbe awọn nnkan eewọ ju silẹ jẹ okunfa fun wiwọ inu alujanna.