عن أبي هريرة رضي الله عنه عن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«مَا نَقَصَتْ صَدَقَةٌ مِنْ مَالٍ، وَمَا زَادَ اللهُ عَبْدًا بِعَفْوٍ إِلَّا عِزًّا، وَمَا تَوَاضَعَ أَحَدٌ لِلهِ إِلَّا رَفَعَهُ اللهُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2588]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Sàárà kii din dúkìá kù, Ọlọhun kii le ẹrú kún pẹ̀lú amojukuro àyàfi ni iyì, ẹnikan ko nii tẹrí ba fun Ọlọhun àyàfi ki Ọlọhun gbe e ga”
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2588]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe saara kii din dúkìá ku, bi ko ṣe pe o maa n ti àwọn nǹkan ti o le ba a jẹ́ danu, Ọlọhun si maa n fi oore ńlá rọ́pò fun ẹni tí n ṣe saara, o maa wa jẹ alekun ni kii ṣe adinku.
Amojukuro pẹlu ikapa lati gba ẹsan kii le ẹni ti o ba ṣe e kun nǹkan kan ayafi ni agbara.
Ẹnikan ko nii tẹrí ba tori ti Ọlọhun, ti kii ṣe ti ibẹru ẹnikẹ́ni, tabi ti ẹ̀tàn, tabi wiwa anfaani kan lọ́dọ̀ rẹ, àyàfi ki ẹsan rẹ o jẹ gíga ati iyì.