+ -

عن أبِي هُرَيرةَ رضي الله عنه أنَّ رسول الله صلى الله عليه وسلمَ قال:
«إذا قُلْتَ لِصَاحِبِكَ: أَنْصِتْ، يومَ الجمعةِ، والْإِمامُ يَخْطُبُ، فَقَدْ لَغَوْتَ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 851]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ti o ba sọ fun ọrẹ rẹ pe: Dakẹ, ni ọjọ jimọ, ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, o ti sọ ọrọ kọrọ».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 851]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye wipe dajudaju ninu awọn ẹkọ ti o jẹ dandan fun ẹni ti o ba wa gbọ khutuba jimọ ni: Didakẹ jẹjẹ fun ẹni ti n ṣe khutuba; lati le ba maa ronu si awọn iṣiti yẹn, ati pe dajudaju ẹni ti o ba sọrọ - koda ko jẹ ọrọ diẹ - ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, ti o wa sọ fun ẹni ti o yatọ si i pe: "Dakẹ" ki o si tun "tẹti", ọla irun jimọ ti bọ fun un.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe ọrọ sisọ ni eewọ ni asiko ti a ba n gbọ khutuba, koda ki o jẹ pẹlu kikọ kuro nibi ibajẹ tabi didahun salamọ ati ṣíṣe adua fún ẹni ti o ba sin.
  2. Wọn ṣe ayaafi nibi eleyii ẹni ti o ba n ba imaamu sọrọ tabi ẹni ti imaamu ba n ba sọrọ.
  3. Lilẹtọọ ọrọ sisọ laarin khutuba mejeeji ti a ba bukaata si i.
  4. Ti wọn ba darukọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti imaamu si n ṣe khutuba lọwọ, dajudaju waa tọrọ ikẹ ati ọla fun un ni jẹ́jẹ́, bakannaa ni ṣiṣe aamiin si adua.
Àlékún