+ -

عَنِ ابْنِ عُمَرَ رضي الله عنهما عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، قَالَ:
«مَثَلُ الْمُنَافِقِ، كَمَثَلِ الشَّاةِ الْعَائِرَةِ بَيْنَ الْغَنَمَيْنِ تَعِيرُ إِلَى هَذِهِ مَرَّةً وَإِلَى هَذِهِ مَرَّةً».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2784]
المزيــد ...

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o sọ pe:
“Apejuwe ṣọbẹ-ṣelu da gẹgẹ bii apejuwe aguntan ti o n lọ ti o n bọ laaarin agbo aguntan meji, yoo lọ sibi fun ìgbà kan, yoo tun lọ si ọ̀hún nigba mii”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2784]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé iṣesi ṣọbẹ-ṣelu pe o da gẹgẹ bii aguntan ti o n ṣe iyemeji ti ko mọ eyi ti o maa tẹle ninu agbo aguntan méjèèjì, O maa lọ ba agbo yii nigba mii, a tun lọ ba omiran nigba mii, Wọn wa ninu idaamu-daabo laaarin igbagbọ ati aigbagbọ, wọn ko si pẹlu awọn olugbagbọ ni ti gbangba ati ni kọkọ, wọn ko si tun si pẹlu awọn alaigbagbọ ni gbangba ati ni kọkọ, bi ko ṣe pe gbangba wọn wa pẹlu awọn olugbagbọ, ti kọkọ wọn si wa nibi iyemeji ati aisi lojukan, nigba mii wọn maa yi lọ sọ́dọ̀ awọn yii, nigba mii wọn maa yi lọ sọ́dọ̀ awọn yii.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ninu itọsọna Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni fifi àpẹrẹ lelẹ lati mu awọn ìtumọ̀ sunmọ.
  2. Alaye iṣesi awọn ṣọbẹ-ṣelu bii aisi lojukan ati iyemeji ati aiduroṣinṣin.
  3. Ikilọ nipa iṣesi awọn ṣọbẹ-ṣelu ati ṣiṣeni lojukokoro lori ododo ati ipinnu nibi igbagbọ ni gbangba ati ni kọkọ.