+ -

عن ابن عباس رضي الله عنهما قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«ما مِنْ أيَّامٍ العمَلُ الصَّالِحُ فيها أحبُّ إلى اللهِ مِن هذه الأيام» يعني أيامَ العشر، قالوا: يا رسُولَ الله، ولا الجهادُ في سبيلِ الله؟ قال: «ولا الجهادُ في سبيلِ الله، إلا رجلٌ خَرَجَ بنفسِه ومالِه فلم يَرْجِعْ من ذلك بشيءٍ».

[صحيح] - [رواه البخاري وأبو داود، واللفظ له] - [سنن أبي داود: 2438]
المزيــد ...

Lati ọdọ ọmọ Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
«Ko sí ọjọ kankan ti iṣẹ oloore inu rẹ jẹ eyi ti Ọlọhun nifẹẹ si julọ ti o to awọn ọjọ yii» ìyẹn ni awọn ọjọ mẹwaa akọkọ Dhul Hijjah, wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ati jijagun si oju ọna Ọlọhun náà? O sọ pe: «Ati jijagun si oju ọna Ọlọhun, ayaafi arakunrin kan ti o jade pẹlu ẹmi rẹ ati dukia rẹ ti ko si ṣẹri pada pẹlu nkankan ninu rẹ».

[O ni alaafia] - [Bukhaariy ati Abu Daud ni wọ́n gba a wa, tiẹ si ni gbólóhùn naa] - [Sunanu ti Abu Daud - 2438]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye wipe dajudaju iṣẹ oloore ṣiṣe ninu ọjọ mẹwaa akọkọ ninu oṣu Dhul Hijjah lọla ju awọn ọjọ ọdun yooku lọ.
Ni awọn saabe - ki Ọlọhun yọnu si wọn - wa beere lọwọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nipa jijagun si oju ọna Ọlọhun ninu ọjọ ti o yatọ sí àwọn ọjọ mẹwaa yii wipe ṣe oun ni o ni ọlá julọ ni àbí awọn iṣẹ oloore ninu awọn ọjọ yii? Latari ohun ti o rinlẹ lọdọ wọn wipe jijagun si oju ọna Ọlọhun wa nínú àwọn iṣẹ ti o lọla julọ.
Nigba naa ni o wa fesi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe: Dajudaju iṣẹ oloore ṣiṣe ninu awọn ọjọ yii lọla ju jijagun si oju ọna Ọlọhun ninu ọjọ ti o yatọ si i lọ, ayaafi arakunrin kan ti o jade ni ẹni ti n jagun ti o si n fi ẹmi rẹ ati dukia rẹ wewu ni oju ọna Ọlọhun, ti o wa padanu dukia rẹ ti ẹmi rẹ naa si tun bọ sí oju ọna Ọlọhun, Irufẹ iṣẹ yii ni yio lọla ju iṣẹ oloore ninu awọn ọjọ ọlọla yii lọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti n bẹ fun iṣẹ oloore ninu ọjọ mẹwaa Dhul Hijjah, nitori naa o jẹ dandan fun Musulumi ki o ṣe amulo awọn ọjọ yii ki o si tun pọ ni iṣẹ oloore ninu rẹ, bii riranti Ọlọhun ti O lágbára ti O si tun gbọnngbọn, ati kika Alukurāni, ati ṣiṣe gbólóhùn "Allāhu Akbar", ati gbolohun "lā ilāha illā Allāhu", ati gbolohun "AlhamduliLlāhi, ati kiki irun, ati ṣiṣe saara, ati gbigba aawẹ, ati gbogbo awọn iṣẹ oloore yòókù.
Àlékún