عن ابنِ عُمَرَ رضي الله عنهما قال: قال رسولُ الله صلَّى الله عليه وسلم:
«مَن تَشَبَّهَ بِقَوْمٍ فَهُوَ مِنْهُمْ».
[حسن] - [رواه أبو داود وأحمد] - [سنن أبي داود: 4031]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara wé àwọn ènìyàn kan jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.”
[O daa] - [Abu Daud ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 4031]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni ti o ba fara wé àwọn èèyàn kan ninu awọn keferi, tabi awọn arúfin, tabi awọn ẹni rere- pẹ̀lú pe ki o ṣe nǹkan kan ninu awọn ìròyìn ti a mọ̀ wọn mọ̀ nibi adisọkan, tabi awọn ijọsin tabi awọn àṣà - ọkan ninu wọn ni; tori pé àfarawé wọn lóde máa ń yọrí sí àfarawé wọn ní inú, kò sì sí àní-àní pé àfarawé àwọn èèyàn máa ń jẹyọ latara ìjọlójú ni. Ó sì lè jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa gbé wọn tobi, kí wọ́n sì tẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wọn, èyí sì lè mú kí èèyàn máa fara wé wọn titi dori inú ti o pamọ àti ìjọsìn – ki Ọlọhun ṣọ wa kúrò nibẹ-.