+ -

عن أبي هريرة رضي الله عنه عن النبي صلى الله عليه وسلم:
«اللهُمَّ لَا تَجْعَلْ قَبْرِي وَثَنًا، لَعَنَ اللهُ قَوْمًا اتَّخَذُوا قُبُورَ أَنْبِيَائِهِمْ مَسَاجِدَ».

[صحيح] - [رواه أحمد] - [مسند أحمد: 7358]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, ó gba a wá lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a:
“Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà, Ọlọhun ti ṣẹbi lé awọn ijọ kan tí wọ́n sọ saare awọn Anabi wọn di mọṣalaṣi”.

[O ni alaafia] - [Ahmad ni o gba a wa] - [Musnad ti Ahmad - 7358]

Àlàyé

Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, képe Oluwa rẹ̀ pé kí o má ṣe sọ saare oun dà gẹ́gẹ́ bí oriṣa ti awọn eniyan n sìn nipa gbigbe titobi fun un ati fífi orí kanlẹ fun un. Lẹhin naa, Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, fún wa ní ìró pé Ọlọhun ti gbe ikẹ Rẹ̀ jìnnà sí awọn tí wọ́n sọ saare awọn Anabi di mọṣalaṣi; nitori sísọ ọ di mọṣalaṣi lè di ọna awawi lati jọsin fún wọn, ati níní adiọkan sí wọn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan الأكانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Títayọ aala ofin sharia nibi saare awọn Anabi ati awọn ẹni rere yoo jẹ ki awọn eniyan maa jọsin fún wọn dipo Ọlọhun, nitori naa, ọranyan ni kí a wá ìṣọra kuro nibi awọn ọna ẹbọ.
  2. Kò tọ́ láti lọ síbi saare nitori gbígbé títóbi fun un ati ṣiṣe ìjọsìn níbẹ̀, bó ti lè wù kí ẹni tí ó wà ninu saare naa sunmọ Ọlọhun Ọba tó.
  3. Eewọ ni kíkọ́ mọṣalaṣi sori àwọn saare.
  4. Eewọ ni kí a máa kírun níbi saare, kódà bí wọn ò bá kọ́ mọṣalaṣi, ayafi kíkí ìrun sí òkú tí wọn ò tíì kirun sí lara.