+ -

عن أبي موسى الأشعري رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«إِذَا مَرِضَ الْعَبْدُ أَوْ سَافَرَ كُتِبَ لَهُ مِثْلُ مَا كَانَ يَعْمَلُ مُقِيمًا صَحِيحًا».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 2996]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Musa Al-ash’ari - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
"Tí ẹrú Ọlọhun kan bá ṣàìsàn tabi ó rin irin-ajo, wọn yoo kọ laada silẹ fun un fún iṣẹ tí n ṣe nigba tí ó wà nílé tó sì lalaafia".

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 2996]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọrọ nipa oore-ọfẹ Ọlọhun ati ikẹ Rẹ̀ lori musulumi, tí ó fi jẹ́ pé tí ó bá wà ninu àṣà musulumi pé ó máa ń ṣiṣẹ́ rere kan ní ẹni tó ní alaafia, tí kò sì rinrin ajo, musulumi naa wáá ní awawi kan latara pé ó ṣaisan, kò wá lè ṣe iṣẹ rere naa, tabi pé ó ṣairoju pẹlu irin-ajo, tabi èyíkéyìí ninu awọn awawi; dajudaju wọn maa kọ laada iṣẹ rere naa silẹ fun un ní pípé, bí ẹni pé ó ṣiṣẹ naa ni awọn asiko tó ni alaafia, tí kò sì wà ní irin-ajo.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Gbígbòòrò oore-ọfẹ Ọlọhun lori awọn ẹru Rẹ̀.
  2. Rírọni lati maa gbiyanju ṣe awọn ijọsin fun Ọlọhun, kí a sì maa lo awọn asiko wa dáadáa nigba tí a bá wà ní alaafia, tí a sì ráyè.