عن عثمان بن عفان رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَنْ تَوَضَّأَ فَأَحْسَنَ الْوُضُوءَ خَرَجَتْ خَطَايَاهُ مِنْ جَسَدِهِ حَتَّى تَخْرُجَ مِنْ تَحْتِ أَظْفَارِهِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 245]
المزيــد ...
Lati ọdọ Uthman ọmọ Affan- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
“Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 245]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe aluwala pẹlu ṣíṣe àkíyèsí awọn sunna aluwala ati awọn ẹkọ rẹ, iyẹn maa wa ninu awọn okunfa pipa awọn ẹṣẹ rẹ ati pipa àṣìṣe rẹ, titi awọn ẹṣẹ rẹ yoo fi jade labẹ awọn èékánná ọwọ rẹ mejeeji ati ti ẹsẹ rẹ méjèèjì.