1. Ojú ìwé wẹẹbu àkọ́kọ́
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Hadiisi “Ẹ má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ sì má sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dajudaju asalatu yín ó kàn mi lara lati ibikibi ti ẹ ba wa

عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«لَا تَجْعَلُوا بُيُوتَكُمْ قُبُورًا، وَلَا تَجْعَلُوا قَبْرِي عِيدًا، وَصَلُّوا عَلَيَّ؛ فَإِنَّ صَلَاتَكُمْ تَبْلُغُنِي حَيْثُ كُنْتُمْ».

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ṣo pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
“Ẹ má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ sì má sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dajudaju asalatu yín ó kàn mi lara lati ibikibi ti ẹ ba wa.

O daa Abu Daud ni o gba a wa Sunanu ti Abu Daud - 2042

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fún wa níbi kí a má maa ki ìrun ninu awọn ile wa, tí awọn ile naa yio waa da gẹgẹ bii itẹ́ awọn òkú, tí ẹnikẹni kò gbọdọ̀ kirun nibẹ. O sì kọ̀ fun wa lati maa ṣe àbẹ̀wò saare rẹ̀ léraléra ati imaa kójọ sibẹ ni igba gbogbo; nitori pe iyẹn jẹ́ ọna kan tí ó lè mu wa wọ inu ẹbọ. Ó paṣẹ pe ki a maa tọrọ ìkẹ́ ati ìgẹ̀ fun oun ni ibikibi lori ilẹ aye; nitori pe iyẹn yoo kàn án lara lati ọdọ ẹniti ó sunmọ ati ẹniti ó jinna bakan naa, nitori naa a o ni bukata si ki a maa paara ibi saare rẹ̀.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. kíkọ̀ fun wa kuro nibi kí a má maa jọsin fun Ọlọhun Ọba ninu awọn ile wa.
  2. kíkọ̀ fun wa kuro nibi ìrìn-àjò lati lọ ṣabẹwo saare Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nítorí pé ó paṣẹ fun wa pe ki a maa ṣe asalatu fun oun, ó sì sọ pe yoo kan oun lara, ṣugbọn a lè ṣe irin-ajo lati lọ ṣabẹwo mọṣalaṣi Anabi kí a sì kirun ninu rẹ̀.
  3. Èèwọ̀ ni ki a sọ abẹwo saare Anabi di ọdun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nipa pípàárà abẹwo saare rẹ̀ ni ọna kan ati asiko kan pato, bakan naa ni ṣiṣe abẹwo gbogbo saare.
  4. Apọnle ti n bẹ fun Anabi lọdọ Oluwa rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pẹlu ṣíṣe ìtọrọ ìkẹ́ ati ìgẹ̀ fun Anabi lófin ní gbogbo ìgbà ati àyè.
  5. Níwọ̀n ìgbà tí ìkọ̀fúnni kuro nibi kíkírun nibi awọn saare ti fẹsẹ rinlẹ lọdọ awọn sahaaba; idi niyi ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - fí ń kọ̀ fun wa pé a ò gbọdọ̀ ṣe awọn ile wa gẹgẹ bii itẹ́ saare tí wọn ò kí ń kírun nibẹ.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

69 Èdè
EN English الإنجليزية
UR اردو الأوردية
ES Español الإسبانية
ID Indonesia الإندونيسية
UG ئۇيغۇرچە الأيغورية
BN বাংলা البنغالية
FR Français الفرنسية
TR Türkçe التركية
RU Русский الروسية
BS Bosanski البوسنية
SI සිංහල السنهالية
HI हिन्दी الهندية
ZH 中文 الصينية
FA فارسی الفارسية
VI Tiếng Việt الفيتنامية
TL Tagalog تجالوج
KU Kurdî الكردية
HA Hausa الهوسا
PT Português البرتغالية
ML മലയാളം المليالم
TE తెలుగు التلغو
SW Kiswahili السواحيلية
TA தமிழ் التاميلية
MY မြန်မာ البورمية
TH ไทย التايلندية
DE Deutsch الألمانية
JA 日本語 اليابانية
PS پښتو بشتو
AS অসমীয়া الأسامية
SQ Shqip الألبانية
SV Svenska السويدية
AM አማርኛ الأمهرية
NL Nederlands الهولندية
GU ગુજરાતી الغوجاراتية
KY Кыргызча القيرقيزية
NE नेपाली النيبالية
LT Lietuvių الليتوانية
PRS دری الدرية
SR Српски الصربية
SO Soomaali الصومالية
TG тоҷикӣ الطاجيكية
RW Kinyarwanda الكينياروندا
RO Română الرومانية
HU Magyar المجرية
CS Čeština التشيكية
MOS Moore الموري
MG Malagasy المالاجاشية
FF Fulfulde الفولانية
IT Italiano الإيطالية
OM Oromoo الأورومو
KN ಕನ್ನಡ الكانادا
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan الأذربيجانية
EL Ελληνικά اليونانية
AK Akan الأكانية
UZ O‘zbek الأوزبكية
UK Українська الأوكرانية
KA ქართული الجورجية
LN Lingala اللينجالا
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
DA Dansk الدنماركية
RN Kirundi الكيروندي
KMR Kurmancî الكرمنجية
MS Bahasa Melayu الملايو