عن عمران بن حصين رضي الله عنه قال: كَانَتْ بِي بَوَاسِيرُ، فَسَأَلْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ عَنِ الصَّلَاةِ، فَقَالَ:
«صَلِّ قَائِمًا، فَإِنْ لَمْ تَسْتَطِعْ فَقَاعِدًا، فَإِنْ لَمْ تَسْتَطِعْ فَعَلَى جَنْبٍ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 1117]
المزيــد ...
Lati ọdọ ‘Imrān ọmọ Husoyn – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Aisan jẹ̀díjẹ̀dí mu mi, nigba naa ni mo wa bi Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – leere nipa irun, ni o wa sọ pe:
«Ki irun ni iduro, ti oo ba wa ni ikapa, yaa ki i ni ijokoo, ti oo ba tun wa ni ikapa, ki i ni ifẹgbẹlelẹ».
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1117]
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye wipe dajudaju ipilẹ ninu irun ni iduro, ayaafi ni igba ti ko ba si ikapa, nigba naa yio ki i ni ẹnití o jokoo, ti ko ba tun ni ikapa kiki irun ni ẹni ti o jokoo, o le ki i ni ifẹgbẹlelẹ.